Ẹ fura o: obinrin ni wọn fi tan olori Biafra, Nnamdi Kanu

Bi iroyin ti a n gbọ yii ba fi ẹsẹ mulẹ tan, nnkan abuku pata lọrọ naa yoo pada jẹ, nitori aṣiri to n jade bayii ni pe Olori awon ọmọ  Biafra, Nnamdi Kanu, ti ijọba apapọ mu, wọn lobinrin ni wọn fi tan an o.

NI ilu  London ni Kanu n gbe, ọmọ oniluu si ni nibẹ, eyi to tumo si pe ọmọ United kingdom ni. Nitori bẹẹ, iṣoro ni fun ijọba Naijira lati lọ sibẹ lọọ mu un, tabi lati bẹ awon ọlopaa agbaye niṣẹ lati mu un ni London tabi ibiki lorilẹ-ede UK, eyi lo si fun un ni anfaani lati maa ṣe gbogbo ohun to n ṣe.

Ṣugbọn gbogbo  ọna ni ijọba n wa lati mu un, agaga nigba ti wọn fẹsun kan an pe oun lo n da wahala to n ṣẹlẹ nilẹ Ibo silẹ, oun lo n sọ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ Biafra maa pa awọn ọlọpaa ati ṣọja ti wọn ba ti ri. Nitori bẹẹ ni wọn si ṣe dẹ awọn ọlọpaa agbaye ti wọn n  pe ni Intapo (Interpol) si i. Awọn ọlọpaa yii ni wọn lo arẹwa obinirin kan.

Obinrin yii ni wọn lo fi ọrọ didun ati ohun ifẹ ba Kanu sọrọ, ni Kanu fi gba pe oun yoo ri i ni orilẹ-ede mi-in, nibi ti oju aye ko ti i ni si lara oun. Orilẹ-de yii lo lọ, Brazil ni wọn pe e, lati lọọ pade ọrẹbinrin tuntun yii, afi bo ṣe debẹ to ko sinu akolo awọn amunifọba agbaye.

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: