Ẹ fura o! Ọgbọn eeyan tun lugbadi arun Korona lọjọ kan ṣoṣo ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọgbọn eeyan lo tun ko arun Koronafairọọsi l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nipinlẹ Kwara. Eyi mu kawọn to ti ni arun naa di ọgọrun-un kan aabọ bayii.

Atẹjade kan lati ọwọ Alukoro igbimọ Covid-19 nipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye, ni eeyan mọkanlelọgbọn lo ti ba arun naa lọ latigba ti kinni ọhun ti wọle.

O ni awọn ijọba ibilẹ mẹtẹẹta to wa niluu Ilọrin; Ilọrin West, Ilọrin South ati Ilọrin East ni kinni ọhun ti pọ, lẹyin naa lo kan Ọffa, Ẹdu, Ifẹlodun, atawọn mi-in.

Ijọba ibilẹ mẹrinla ninu mẹrindinlogun to wa ni Kwara ni arun naa ti tan de.

Lapapọ, ẹgbẹrun kan le igba lo ti ko arun naa, ọpọlọpọ lara wọn lo si ti gbadun, ti wọn ti gba ile wọn lọ.

Esi ayẹwo ọgọrun-kan le mọkandinlọgbọn ni wọn ṣi n reti bayii.

Leave a Reply