Ẹ gba mi o: awọn ọlopaa SARS ti ọmọ mi mọle nitori owo biribiri ti wọn fẹẹ gba ti ko fun wọn

Ile-ẹjọ giga Eko lo pariwo lọ o. Obinrin oniṣowo Eko kan, Regina Stanley ni. O pariwo pe ki awọn adajọ gba oun, ki wọn ba oun yọ ọmọ oun ti awọn ọlọpaa SARS ti mu lati inu oṣu kẹta ọdun yii, ti wọn ko si fi i silẹ nitori ti awọn ko ni ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun Naira (N500,000) ti wọn ni ki awọn waa san fun wọn.

Regina ni ọmọ oun yii, Sunday, lo maa n ran oun lọwọ ni ṣọọbu nibi ti oun ti n taja ni Morogbo, awọn si jọ maa n lọ ni. O ni lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii lawọn de ṣọọbu, oun si ran ọmọ naa niṣẹ, afi bi awọn ọlopaa SARS si ṣe ri i lọna ti wọn mu un. O ni bi awọn aladuugbo ṣe waa sare sọ foun ni ṣoọbu pe wọn mu ọmọ oun loun sare de ọdọ wọn lati sọ pe oun loun ran ọmọ oun niṣẹ, ṣugbọn gbogbo alaye ti oun ṣe fun wọn, wọn ko da oun lohun, nitori wọn ti tun mu awọn mi-in ti wọn n gba owo nla lọwọ wọn.

Obinrin naa ni bi wọn ṣe mu ọmọ oun lọ si agọ wọn ni Ikẹja niyi, ti wọn si ka oriṣiiriṣii ẹsun ti ko mọdi si i lẹsẹ, ti wọn wa ni ko tete lọọ mu owo wa, bi bẹẹ ko, ewọn lo n lọ. Regina ni nigba ti wọn yoo beere owo, ti wọn ni afi ki awọn wa ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) wa, loun mọ pe ọrọ naa ki i ṣe kekere. O ni bo tilẹ jẹ pe oun ṣalaye fun wọn pe opó loun, ọko oun ti ku lati ọdun to kọja, awọn ọlọpaa SARS yii ko da oun lohun, wọn ni afi ki oun wa owo yii wa adandan, nigba ti oun ko si le ri owo yii loun ṣe sa wa siwaju awọn adajọ o.

Olukọya Ogungbẹjẹ ni agbẹjọro to gba, iyẹn si ti ni ki awọn adajọ da a pe mimu ti awọn SARS mu Sunday ko ba ofin mu, ki wọn si paṣẹ pe ki wọn fi i silẹ kia.

 

One thought on “Ẹ gba mi o: awọn ọlopaa SARS ti ọmọ mi mọle nitori owo biribiri ti wọn fẹẹ gba ti ko fun wọn

Leave a Reply