Ẹ gba mi o, wọn fa irun ọmọ mi lẹgbẹẹ kan, wọn tun sin gbẹrẹ si i lori nileewe to n lọ-Sandrah

Jọkẹ Amọri

Ko sẹni to ti i le sọ ibi ti wahala kan to n ṣẹlẹ bayii laarin obinrin kan, Sandrah Ọlatunji, ti ọmọ rẹ obinrin ti ko ju ọmọ ọdun meji lọ n lọ si ileewe ti wọn n pe ni Shunshine Group of Schools, ẹka wọn to wa ni Ireakari, niluu Ibadan, yoo yọri si pẹlu bi obinrin naa ṣe pariwo sita pe ẹnikan ti fa irun ọmọ oun toun gbe lọ si ileewe naa, wọn si sin gbẹrẹ meji si i lori.

Ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan ni obinrin naa ti ṣalaye pe, ‘‘Ọmọ mi ti ko ju ọmọ ọdun meji lọ n lọ si ileewe kan ti wọn n pe ni Shunshine Group of Schools, ẹka wọn to wa ni Ireakari, niluu Ibadan. Mo mu ọmọ mi lọ sileewe laaarọ ana, ko si si ohun to ṣẹlẹ si i. Lẹyin naa ni mo gba ṣọọṣi lọ. Nigba to di bii aago marun-un ku ogun iṣẹju ni mo pada lọ sileewe naa pe ki n lọọ mu ọmọ mi. Nigba naa ni mo ṣakiyesi pe ẹnikan ti fa irun ọmọ mi lẹyin, ti wọn si sin gbẹrẹ meji si oju ibẹ. Ẹ jọwọ, ẹ ran mi lọwọ o, niṣe ni wọn sọ fun mi pe ẹrọ aṣofofo (CCTV) awọn ko ṣiṣẹ lanaa ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Sibẹ ojoojumọ lo n ṣiṣẹ tẹlẹ o, eyi ti wọn ka silẹ lanaa ni wọn ko ri mu jade, ti wọn ni ẹrọ naa ko ṣiṣẹ nigba ti a jọ wo o. Awọn alaṣẹ ileewe naa ko ṣe ohunkohun fun ẹni to ṣiṣẹ naa’’.

Niṣe ni obinrin naa mu ariwo bọnu lori Insagraamu pe ki awọn eeyan ran oun lọwọ lori ọrọ naa nitori oriṣiiriṣii ibeere lo yẹ ki ileewe yii dahun lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn ti wọn n gbiyanju lati bo o mọlẹ.

O ni, ‘‘Gbogbo ọmọ Naijiria, ẹ jọwọ, ẹ gba mi o, wọn ti fẹẹ bo ọrọ yii mọlẹ, awọn kan tiẹ ti fẹẹ pa ikanni Instagraamu mi rẹ ki awọn eeyan ma baa ri ohun ti mo kọ yii’’.

Oriṣiiriṣii imọran ni awọn kan ti n fun iya ọmọ ti wọn fa irun rẹ yii, bawọn kan ṣe n sọ pe niṣe lo yẹ ko sọ gbogbo were kalẹ lori iṣẹlẹ naa fawọn alaṣẹ ileewe ọhun lawọn kan n sọ fun un pe ko lọọ fọrọ naa to ọlọpaa leti nitori ti irun ọmọ naa ba ti hu pada, ko si ẹri to fẹẹ fi han mọ.

Bẹẹ ni ẹnikan to pe ara rẹ ni temitọpẹ_omo gba obinrin naa niyanju pe ko yaa tete gbe ọmọ naa lọ si ṣọọṣi fun itusilẹ. O ni, ‘‘Jọwọ tete gbe ọmọ naa lọ si ṣọọṣi fun itusilẹ to o ba jẹ Kirisitẹni, to ba si jẹ Musulumi naa ni ọ, tete gbe e lọ si mọṣalaasi. Jọwọ, ṣe eleyii siwaju ohunkohun. O jọ pe eleyii ki i ṣe oju lasan’’

Ẹnikan to tun sọrọ sabẹ aworan ọmọ naa to pe ara ẹ ni christyoflove sọ pe ‘‘Ọlọpaa ma ko gbogbo eeyan ni o, ti wọn ko ba le gbe ẹrọ aṣofofo jade lati wo aworan ohun to ṣẹlẹ. Gbogbo wọn, to fi mọ gbogbo awọn olukọ, atawọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ ninu ọgba ileewe naa lo yẹ ki wọn ko gẹge bii afurasi.

‘‘Awọn ẹlẹgbẹ akẹkọọ ọmọ ọdun meji ko le fa irun ori rẹ bayii, o han gbangba pe iṣẹ ọwọ agbalagba ni, mi o si ro pe olukọ to n kọ awọn ọmọ naa ni kilaasi yoo gọ debii ko ṣe iru nnkan bẹẹ. O ṣee ṣe ko jẹ ẹnikan ninu ọgba ileewe naa lo ṣiṣẹ buruku yii. Adura mi ṣaa ni pe ki nnkan kan ma ṣe ọmọ yii.

 

Leave a Reply