Ẹ gbadura fun Baba Ijẹṣa o, ara rẹ ko ya  ko ya gidigidi lẹwọn o

Faith Adebọla

Afi ki gbogbo mọlẹbi atawọn ololufẹ gbajugbaja adẹrin-in poṣonu ilẹ wa nni, James Ọlanrewaju Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa kun fun adura gidigidi lasiko yii o, tori ara ọkunrin naa ko ya lọgba ẹwọn Kirikiri to wa, wọn laisan buruku kan n ba a finra.

Nigba ti akọroyin wa ṣabẹwo si Baba Ijẹṣa lọgba ẹwọn lo ṣalaye fun wa pe aarẹ buruku kan ti n ba oun finra labẹnu koun too dero ẹwọn lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun yii.

Baba Ijẹṣa ni ọsẹ kan lẹyin naa, logunjọ, oṣu Keje, loun lọ sileewosan ti wọn ti n tọju awọn ẹlẹwọn fun ayẹwo ati itọju, o ni gbogbo igba loun n sọrọ aarẹ naa fun wọn, amọ niṣe ni wọn aa kan ṣakọsilẹ wuruwuru kan nipa rẹ, wọn aa ni ki oun maa lọ. O ni ko si itọju gidi kan, tori ko si nnkan eelo iṣegun ti wọn le fi ṣayẹwo nibẹ, o ni wọn kan fun oun ni parasitamọọ ati kinni kan to da bii ororo ni. O loun o fi ọrọ aisan naa pamọ fawọn aburo oun. O loun ti paara ọsibitu awọn ẹlẹwọn “bii ẹẹmẹta ẹẹmẹrin, sibẹ, ti ko siyatọ”.

O ni: “Mo dẹ n sọ fawọn aburo mi ti wọn n waa wo mi pe nnkan bayii n ṣe mi o,” ki wọn le tete mọ. Fun apẹẹrẹ, bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, oju kan naa ti mo mo maa jokoo si latoorọ ṣulẹ naa ni ma a wa titi tilẹ maa fi mọ. Mi o ki i roorun sun, ara n ro mi.

“Nigba mi-in, o maa da bii pe ori mi gbona. Nigba ti ma a jẹun, ti mi o ni i le lọọ ṣegbọnsẹ, igba to ya ni mo lọ sinu igbo kan layiika ọgba ẹwọn nibi, ti mo lọọ ja awọn ewe kan ti mo ro pe mo le lo, ṣugbọn kẹmika ti wọn fi n finko ti ba gbogbo awọn ewe yẹn jẹ, mi o le lo wọn.

“Ko dẹ soogun ti mo le ri ra laduugbo yii, ko si sẹni teeyan le ran niṣẹ nibi, ta lo fẹẹ ba ẹ lọ? Ẹ wo o, gbogbo ẹ ti su mi. Beeyan ba tiẹ maa ku, ṣebi eeyan aa lọọ ku sile ẹ, aa dẹ mọru iku to maa pa oun.

‘‘Ohun ti mi o mọ nipa ẹ ni mo n jiya ẹ, ṣugbọn mo mo pe o ye Ọlọrun. Ọlọrun Olodumare, Ọlọrun to mọ ohun gbogbo, mo mọ pe o maa ṣedajọ fun Princess, adabi ti mo ba fi abẹrẹ lasan kan ọmọbinrin to n purọ ẹ mọ mi pe emi fi kọkọrọ mọto ja ibale ẹ lo yaa ku.”

‘‘Bẹẹ ṣe waa ba mi sọrọ yii, o ya mi lẹnu gan-an ni, tori mo ṣẹṣẹ fẹẹ pe lọọya mi ni, ti mo fẹẹ sọ fun wọn pe bi wọn ṣe n wo mi niran yii, niṣe ni wọn kan maa ṣadeede gbọ pe mo ku, oju wọn dẹ maa walẹ.

“Gbogbo nnkan ti mo la kọja yii ni mo ti ṣalaye ẹ fawọn aburo mi, mo ṣaroye fun Toyin, aburo mi, Akin, mo sọ fun un. Yọmi Fabiyi mọ, gbogbo awọn to n ran mi lọwọ diẹdiẹ naa niyẹn, mo si ti sọ fun lọọya mi, koda niṣe lawọn to n ba mi sọrọ laipẹ yii n beere pe bawo lohun mi ṣe ri bayii, mo ni mi o mọ, o kan n rẹ mi, o n rẹ mi, mi o le jokoo pupọ, mi o le naro pupọ, ṣugbọn kin ni mo fẹẹ ṣe. Mo sọ fun buọda mi naa, Ayọ Oluyẹmi, Ibadan ni wọn wa, pe bawo ni wọn ṣe fẹẹ ba mi ṣe e, mo nilo ki wọn ṣe tẹẹsi fun mi, ko dẹ si tẹẹsi kankan nibi yii o.

“Ẹ ba mi bẹ awọn ọmọ Naijiria, ki wọn ṣaanu mi, ki wọn ma jẹ n ku bayii o, ki wọn dide iranlọwọ fun mi o, iya aimọdi ree o, ṣugbọn, too, mo gba ohun t’Ọlọrun ba ṣe o.”

Bẹẹ ni Baba Ijẹṣa n fi tẹkun-tomije sọrọ

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an yii, ni Adajọ Oluwatoyin Taiwo, tile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle da iwe ẹbẹ tawọn agbẹjọro Baba Ijẹṣa gbe siwaju rẹ lati fun ọkunrin alawada naa ni beeli nu bii omi iṣanwọ, o ni ẹbẹ wọn ko tẹwọn rara, tori wọn o sọ idi pato ti wọn fi ni lati ṣiju aanu wo onibaara wọn.

Ṣugbọn ẹjọ ṣi n lọ  lori iwe ipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Baba Ijẹṣa pe. O ṣee ṣe ko jẹ adajọ mi-in ni yoo tẹsiwaju lori ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ọhun latari bi wọn ṣe ni Adajọ Oluwatoyin ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba.

Leave a Reply