Adewale Adeoye
Olori ileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja tẹlẹ, Sẹnetọ Ahmed Lawan, ti rọ awọn ọmọ orileede yii pe ki wọn kun fun adura, ki olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, le baa ṣe aṣeyọri ninu ijọba to n ṣe lọwọ yii. Sẹnetọ Lawan to n ṣoju ẹkun Yola-North, sọrọ ọhun di mimọ lopin ọsẹ to kọja yii lasiko to n dibo rẹ ninu ibo ijọba ibilẹ to waye nipinle Yobe, laipẹ yii. Lawan, to jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣelu APC loun ni igbagbọ gidi ninu iṣakoso ijọba Tinubu pe yoo gbe orileede Naijiria de ebute ayọ bi awọn ọmọ orileede yii ba ba kun fun adura lori rẹ.
Atẹjade kan ti alukoro eto iroyin rẹ fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, eyi to fọwọ si lo ti sọ pe, ‘’A gbọdọ kun fun adura lori iṣakoso ijọba Tinubu ni, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Aṣiwaju gbogbo agbaaye ni, o n ṣe daadaa ninu iṣakoso ijọba rẹ lọwọ yii, bẹẹ lo n sapa rẹ lati gbe iṣakoso ijọba orileede yii de ebute ayọ. O ṣee ṣe ka ma tete ri esi ayọ ohun to n ṣe lọwọ bayii, ṣugbọn laipẹ, a o ri i pe o n gbiyanju gidi ni.
’’ Loooto, awọn eto rẹ kọọkan le ma tẹ wa lọrun lasiko yii, bẹẹ ni awọn kọọkan daa gidi. Mo fi da gbogbo wa loju pe lopin ohun gbogbo, igbe aye idẹrun lo maa pada ba gbogbo ọmọ orileede Naijiria laipẹ yii, ti ara si maa pada dẹ gbogbo ilu. Awọn ọmọ orileede Naijiria maa pada dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba Allah ati awọn olori wa gbogbo.