Ẹ je ka bẹ Pasitọ Adeboye atawọn olori ẹlẹsin to ku, ki wọn ma ba aṣa Yoruba jẹ o

Ọjọgbọn agbaye kan, Purofẹsọ Toyin Falọla, ti sọ pe gbogbo ẹni yoowu to ba fẹran aṣa ati idagbasoke ilẹ Yoruba gbọdọ dide, ki wọn bẹ Pasitọ Eunoch Adeboye ti i ṣe olori ijọ Ridiimu, ati awọn olori ẹlẹsin ṣọọṣi igbalode to ku, pẹlu awọn aṣaaju ẹsin Islam ti wọn jẹ ọmọ Yoruba, pe ki wọn ma jẹ ki aṣa ati ede Yoruba bajẹ lati ọwọ wọn, nitori bi mejeeji yii ba bajẹ, iṣoro ni yoo jẹ fun ilọsiwaju gbogbo wa. Falọla ni orilẹ-ede nla kan ni iran Yoruba, ṣugbọn bi aṣa wa ba ti bọ sọnu mọ wa lọwo, a ko le jẹ kinni kan laye.

Nibi apero nla kan ti Ọjọgbọn naa ṣe lori ẹrọ ayelujara lati yunifasiti Kembiriiji (Cambridge University) niluu oyinbo lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, yii lo ti sọ bẹẹ, nigba to sọrọ tan ti awọn eeyan bi i leere pe bawo ni ọrọ ẹsin ko ṣe ni i di idagbasoke ilẹ Yoruba lọwọ. O ni awọn olori ẹlẹsin wọnyi ko ṣee ba ja, afi ka bẹ wọn, ka si tubọ ṣalaye fun wọn, ki wọn mọ iyatọ laarin aṣa ati ẹsin, ki wọn yee pe ẹni to ba n ṣe nnkan abalaye wọn ni abọriṣa, nitori pe ko ba ilana ẹsin tiwọn mu.

Ọjọgbọn Falọla ni ọtọ ni iṣẹṣe, ọtọ ni aṣa, bẹẹ ọtọ ni ẹsin, ko si si orilẹ-ede aye tabi iran kan ti ko ni aṣa tiwọn, iran yoowu to ba si ti sọ aṣa ati ohun abalaye rẹ nu, iru iran bẹẹ ko le gberi lawujọ awọn orilẹ-ede aye. O ni ohun ti awọn aṣaaju ẹsin wọnyi fi n kọ awọn eeyan wọn nipa aṣa Yoruba ko ba ilana eto ẹsin to ti wa nilẹ tiwa mu, nitori ko si agboole kan laarin awọn Yoruba teeyan ko ni i ri Musulumi ati Kristẹni, pẹlu awọn ẹlẹsin abalaye, ti gbogbo wọn yoo si maa gbe ni igbe-alaafia. Bo ti wa lati ọjọ alaye ti da a niyẹn.

Ọkunrin Ọjọgbọn yii to n sọrọ lori iwe itan Yoruba nla kan ti wọn ṣẹṣẹ dawọ ṣe niluu oyinbo nibẹ ni awọn ijọba ati eeyan ni orilẹ-ede Cuba, Brazil ati awọn ibomi-in bẹẹ ti mu aṣa ati iṣe Yoruba wọ inu awọn ẹsin igbalode tiwọn lọhun-un, wọn si ti fi idi awọn nnkan wọnyi mulẹ debi pe aṣa ati awọn ohun abalaye Yoruba ko le parun lọdọ wọn. O ni ki gbogbo awọn ti wọn nifẹẹ Yoruba bẹ awọn olori ẹlesin wọnyi, ki wọn ma sọ aṣa Yoruba di nnkan ibọriṣa lasan, ko ma di ohun ti gbogbo awọn ọmọde ati ọdọ yoo maa sa nidii awọn nnkan adayeba wa.

 

5 thoughts on “Ẹ je ka bẹ Pasitọ Adeboye atawọn olori ẹlẹsin to ku, ki wọn ma ba aṣa Yoruba jẹ o

  1. Kokuku nibaje funyin. Awon ti enbawi na mo wipe nkan ti awon nse kodara to. Emi o nowosi wipe kabewon o . Nigbati ija alale yoruba bade tan patapata siwon lorun. Eyin gangan mabawon kaanu..awon irunmole npadabo laipe. Tiwonbaso wipe talosobe. Kesowipe emi ajijolaifa nio

  2. Ohun buruku ti e ni ede oyinbo ti won gbe sori ede Yoruba ninu iwaasu won, ASA idile SE Pataki beeni eewo idile se Pataki, LARA awon ohun to baa aye je loni ti ASA wa FI di akisa ko koja,ona ti awon olori esin wa n gba SE iwaasu tabi waasi Lori esin ajeeji.

  3. Ohun a ní làá náání, ohùn ló fàá tómo aségità fi n náání èèpo igi. Àsà àti èdè ìran se pàtàkì. E jé ká gbé Àsà, èdè àti ìse Yorùbá láruge. Oòduà yóò gbè wá o.

Leave a Reply