Ẹ jẹ ka fọwọsowọpọ pẹlu ẹnikẹni to ba wọle ibo abẹle APC-Ọṣinbajo

Monisọla Saka
Igbakeji Aarẹ ilẹ yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti sọ pe, pẹlu iye awọn eeyan to n dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, awọn gbọdọ ri i daju pe awọn gbaruku ti ẹnikẹni to ba jawe olubori ninu ibo abẹle to n bọ lọna.
Oludamọran pataki lori eto iroyin fun Ọṣinbajo, Laolu Akande, lo sọrọ naa ninu atẹjade kan to gbe jade lorukọ Igbakeji Aarẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii lakooko to lọ fun ipolongo ibo nipinlẹ Rivers l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2022.
Ninu ọrọ ẹ, Ọṣinbajo ni ko yẹ ki ọrọ a n kanra mọra ẹni waye laarin awọn oludije nitori ohun ti gbogbo awọn n le naa ni iṣọkan orilẹ-ede yii.
Ni itẹsiwaju erongba rẹ lati dupo aarẹ lo mu ko ṣe abẹwo lọ si ipinlẹ Rivers, ko le lọọ ri awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Atẹjade ti wọn pe akọle ẹ ni, ‘APC nikan lo ni ohun rere lọkan ju lati ṣe fun Naijiria’ ni Ọṣinbajo ti pe fun iṣọkan nipinlẹ Rivers, Igbakeji Aarẹ waa tẹ ẹ mọ awọn eeyan leti pe gbogbo awọn ti wọn ti kede erongba wọn lati dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn jẹ onitẹsiwaju eniyan.

Leave a Reply