Ẹ kede mi gẹgẹ bii aarẹ tabi tabi ki atundi ibo waye-Atiku Abubakar  

Ọrẹoluwa Adedeji

Oludije siipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, to tun ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ lorileede yii, Alaaji Aiku Abubakar. naa ti gba ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun to ba su yọ lasiko idibo lọ, o si ti ko iwe ẹsun rẹ siwaju wọn nipa eto idibo aarẹ to waye ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii. Lara awọn ohun ti Atiku n beere pe ki ile-ẹjọ naa ṣe fun oun ni yala lati paṣẹ atundi ibo lawọn ibi kan laarin oun ati oludije ẹgbẹ APC, Bọla Tinubu, tabi ki wọn kede oun gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa. O ni bi ọkankan ninu eleyii ko ba waa ṣee ṣe, ki wọn kuku fagi le esi idibo ọhun, ki wọn ṣẹṣẹ waa ṣeto idibo mi-in.

Lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ni awọn agbẹjọro rẹ, eyi ti Joe Gadzama (SAN) lewaju, ko iwe ẹsun wọn ti nọmba rẹ jẹ CA/PEPC/05/2003,  lọ si kootu to fikalẹ siluu Abuja ọhun.

Lori koko pataki mẹrin ni wọn fi n pe abajade esi idibo naa lẹjọ.

Koko akọkọ ni pe eto idibo to gbe Tinubu wọle ko tẹwọn to, nitori ajọ eleto idibo ko tẹle ofin eto idibo ti wọn ṣagbekalẹ rẹ lọdun 2022.

Lọna keji, wọn ni eto idibo to gbe Aṣiwaju Tinubu to wa lara awọn olujẹjọ wọle ko tọna, nitori o kun fun iwa ibajẹ ati magomago.

Bakan naa ni wọn ni Tinubu ti wọn kede gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori yii ko ni ibo to yẹ lati kede rẹ bii ẹni to jawe olubori.

Wọn fi kun un pe ko yẹ ki Tinubu ti wọn kede pe o wọle ibo yii tiẹ dupo rara lasiko ti eto idibo naa waye nitori awọn ẹsun gbigbe oogun oloro ti wọn ti fi kan an.

Nidii eyi ni wọn fi ni esi idibo ti ajọ eleto idibo lo lati kede Tinubu gẹgẹ bii ẹni to bori ko tọna, ko bofin mu, ko si yẹ bẹẹ, niwọn igba ti ko ti ba ofin eto idibo ọdun 2022 mu, ti ko si tun ba ofin orileede Naijiria to sọ pe ẹnikẹni ti yoo ba di aarẹ orileede yii gbọdọ ni ida mẹẹẹdọgbọn (25) ibo ti wọn ba di ni ipinlẹ mẹrinlelogun, eyi ti i ṣe iko meji ninu mẹta awọn ipinlẹ naa, to fi mọ olu ilu ilẹ wa l’Abuja.

Bakan naa ni wọn ni ki ile-ẹjọ yii kede pe loootọ ni Tinubu ko kun oju oṣuwọn lati kopa ninu eto idibo to kọja ọhun.

Pẹlu gbogbo awọn ibeere ti wọn gbe siwaju ile-ẹjọ yii, wọn ni ki kootu naa kede pe Atiku Abubakar lo wọle ibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ki wọn si bura fun un gẹgẹ bii aarẹ Naijiria tuntun.

Ti kootu ko ba ti waa le ṣe eyi, ki wọn kuku paṣẹ pe ki atundi ibo waye lawọn ibi kan laarin oludije awọn (Atiku Abubakar), ati Bọla Tinubu ti wọn kede pe oun lo wọle.

Bi eleyii naa ko ba tun waa ṣee ṣe, ki wọn kuku fagi le eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ kẹẹedọgbọn, oṣu yii, ki eto idibo mi-in si waye.

Awọn ti Atiku pe lẹjọ ni ajọ eleto idibo, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati ati ẹgbẹ APC.

Tẹ o ba gbagbe, oludjije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi naa ti lọ siwaju igbimọ to n gbọ ẹsun magomago to ba su yọ lasiko eto idibo yii.

Lara oun ti awọn naa beere fun ni pe Tinubu ko kun oju oṣuwọn lati dije dupo aarẹ Naijiria, nitori ẹsun gbigbe oogun oloro ti orileede Amẹrika fi kan kan.

Bakan naa ni Peter Obi sọ pe oun loun wọle lasiko ibo ọhun. Bẹẹ lo ni ajọ eleto idibo ko tẹle ofin eto idibo ti wọn ṣe lọdun 2020 atawọn ẹsun mi-in.

Awọn oludije mẹtẹẹta yii lo ti gba awọn agbẹjọro nla nla ti yoo gba ọrọ wọn ro niwaju adajọ. Ohun ti eyi fi han ni pe ọrọ naa yoo rọ ko too to laarin awọn oludije yii.

Leave a Reply