Ẹ ko awọn tẹ ẹ mu nile Sunday Igboho jade o, Ile-ẹjọ paṣẹ fawọn DSS

Ile-ẹjọ giga ilu Abuja kan ti paṣẹ loni-in ọjọ Ẹti, Furaide, yii pe ki ileeṣẹ amunifọba DSS ko gbogbo awọn ti wọn mu nile Oloye Sunday Adeyẹmo ti gbogbo eeyan n pe ni Sunday Igboho sita lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii, ki wọn si mura lati sọ idi ti wọn ṣe ko wọn sinu ahamọ lati ọjọ kin-in-ni oṣu keje yii.

Adajọ Obiora Egwuatu lo paṣẹ bẹẹ nigba to n gbọ ẹjọ ti awọn eeyan ti wọn ti mọle yii pe awọn DSS ati olori wọn pata, Yusuf Bici.  Agbẹjọro wọn, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, lo pe ẹjọ naa lorukọ awọn mejila ti awọn DSS ko lọjọ ti wọn ṣigun nile rẹ, ti wọn si da ibọn bolẹ nibi ti wọn ti pa awọn meji, ti wọn si ko awọn to ku lọ.  Nibẹrẹ oṣu yii leleyii ti ṣẹlẹ, lati igba naa si ni awọn DSS ti ko wọn ti mọle, ti wọn ko si jẹ kẹnikẹni ri wọn.

Nigba ti Adajọ Egwuatu wa n da ẹjo tirẹ, o ni ki awọn DSS ko awọn eeyan naa jade sita gbangba, ki wọn si waa sọ idi loju gbogbo aye ohun ti wọn ṣe, ati idi ti wọn fi ko wọn pamọ ẹ titi bẹẹ. O ni awọn DSS yii gbọdọ waa ṣalaye ki lo fa a ti wọn o fi fẹ ki ile-ẹjọ fun awọn eeyan naa ni beeli, gbogo ohun to ba wa nibẹ ni ki wọn waa sọ. Bo si tilẹ jẹ pe awọn adajọ wa lọlude bayii, Adajọ naa ni oun yoo waa gbọ ẹjọ yii ni Ọjọbọ, Alamisi, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu ti a wa yii gan-an.

 

Leave a Reply