Ẹ kuro loju titi, ẹ jẹ ka jọ sọrọ pọ, Sanwoolu bẹ awọn to n fẹhonu han

 Latari ifẹhonu han lodi si SARS to n lọ lọwọ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti bẹ awọn ọdọ naa pe ki wọn kuro loju titi, ki wọn wa ki awọn jọ sọ asọyepọ lori awọn ẹdun ọkan wọn naa.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni gomina sọrọ naa nigba to n ṣe ifilọlẹ awọn igbimọ ti yoo maa gbọ ẹjọ awọn ti SARS ti ṣe niṣekuṣe tabi ti wọn ti pa mọlẹbi wọn.

O ni awọn ọdọ to n fẹhonu han naa yoo ri i pe gbogbo ọna ni ijọba oun ti fi han pe gbogbo ẹdun ọkan wọn ati ohun ti wọn n beere fun ni ijọba ṣetan lati yanju nitubi-inubi. Eyi lo ni o fa a ti oun fi gbe igbimọ oluwadii kalẹ, ti oun si tun ṣeto owo iranwọ ti awọn ṣetan lati fun awọn ti awọn SARS tẹ ẹtọ wọn mọlẹ labẹ ofin.

Gomina ni gbogbo ohun ti awọn ọdọ yii n beere fun lo tọna, idi si niyi tijọba apapọ ati ti ipinlẹ fi sare gbe igbesẹ lori diẹ ninu awọn ibeere wọn yii, ti akitiyan si n lọ lọwọ lati ri i pe awọn ibeere wọn yooku di ṣiṣe.

Sanwoolu rọ awọn ọdọ yii lati darapọ mọ awọn ti yoo ṣe atunṣe ti wọn n beere fun yii. O ni gbigbe igi di oju ọna ati ifẹhonu han ojoojumọ yii le mu ki atunṣe naa pẹ.

‘‘Mo fẹ kẹ ẹ mọ pe emi naa darapọ mọ yin ninu ohun ti ẹ n beere fun, ẹtọ yin ni, o si tọna labẹ ofin, bi a ṣe gbiyanju lati gbe igbesẹ lori diẹ ninu awọn ohun ti ẹ beere fun, a fẹ ki ẹ ṣe suuru pẹlu wa ki iyooku le di mimuṣẹ.’’ Sanwo-Olu lo parọwa si awọn ọdọ to n fẹhonu han bẹẹ.

Leave a Reply