Adewale Adeoye
Ọga agba patapata fun ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto ounjẹ jijẹ ati oogun lilo lorileede Naijiria ‘National Agency For Food And Administration And Control’ (NAFDAC), Ọjọgbọn Mojisọla Adeyẹye, ti ṣekilọ pataki fawọn ọmọ Naijiria pe wọn ko gbọdọ fi ẹnu kan awọn ounjẹ sise gbogbo ti wọn ba ti gbe sinu firiiji fun ọjọ mẹta mọ, nitori pe o le ṣe ipalara gidi fun ilera wọn lọjọ iwaju.
O ni bii ẹni pe eeyan n ṣẹwọ siku aitọjọ ni beeyan ba n jẹ ounjẹ sise ti wọn gbe sinu firiiji fun ọjọ mẹta ṣe jẹ, nitori pe iku aitọjọ, arun aito oṣu, lo maa pada ṣe onitọhun.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, lo sọrọ naa lasiko ayẹyẹ ayajọ ounjẹ lagbaaye tọdun yii, eyi to waye l’Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa. Ninu atẹjade kan ti Alukoro eto iroyin fun ajọ naa, Ọgbẹni Ṣayọ Akintọla, fọwọ si lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ọga agba ajọ naa ti ṣekilọ pataki ọhun fawọn araalu pe ki wọn yee jẹ ounjẹ sise ti wọn gbe sinu firiiji fun ọjọ mẹta mọ, nitori pe ipalara gidi lo wa ninu rẹ.
Atẹjade ọhun lọ bayii pe, ‘Ọga agba ajọ NAFDAC orileede yii rọ awọn araalu pe ki wọn jawọ ninu jijẹ awọn ounjẹ gbogbo ti wọn gbe sinu firiji fun ọjọ mẹta, o ni o ṣee ṣe ki awọn kokoro airi (Bacteria) kọọkan ti sapamọ sinu irufẹ ounjẹ bẹẹ, o si le ṣakoba gidi fun ilera wọn bi wọn ba jẹ ẹ. Akọba naa si le pada ja si iku fun ọpọ eeyan bi wọn ko ba tete ri itọju gidi gba nileewosan.
Ọjọgbọn Adeyẹye ni idi pataki tawọn ṣe n ṣepolongo yii ni pe jijẹ ojulowo ounjẹ gidi ki i ṣe fun ilera awọn araalu nikan, ṣugbọn o ṣe pataki pupọ fun idagbasoke ati ilọsiwaju orileede lapapọ ni.
O waa rọ awọn eeyan pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu awọn alaṣẹ orileede yii, ki erongba wọn lati fopin si iku aitọjọ to le waye nidii awọn ounjẹ ti ko bojumu rara le wa si imuṣẹ.