Ẹ ma da awọn to sọ pe ijọba ṣofin konilegbele lohun o – Lai Muhammed

Faith Adebọla

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu si bijọba apapọ ṣe sọ wọn sinu okunkun lori aṣẹ konilegbele ti wọn ṣẹṣẹ pa yii, ṣugbọn Minisita feto iroyin nilẹ wa, Alaaji Lai Mohammed, ti sọ pe kawọn araalu ma kọbiara si aṣẹ naa, o ni ki i ṣe ohun tijọba sọ gẹlẹ niyẹn.

Ninu fidio kan to n ja ranyin lori atẹ ayelujara, Lai Mohammed sọ fawọn oniroyin niluu Abuja lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, pe awọn to sọrọ nipa aṣẹ konilegbele ti wọn nijọba apapọ ṣẹṣẹ pa naa ti sọrọ kọja ohun tijọba sọ.

Ṣaaju, lọjọ Aje kan naa, ni Oluṣekokaari ọrọ pajawiri lori arun Korona, Ọgbẹni Mukhtar Mohammed, kede niluu Abuja pe lati ọjọ Tusidee, ofin konilegbele yoo wa lẹnu iṣẹ laarin aago mejila oru si aago mẹrin idaji.

Bakan naa lo ni ijọba ti paṣẹ pe kawọn ile kilọọbu, ile jiimu (gyms), gbọngan ariya, atawọn ibi igbafẹ tero maa n pọ si wa ni titi lasiko yii na, ki ijọba fi wo bi itankalẹ arun yii ṣe n lọ si nilẹ wa ati kari aye.

O ni awọn ileejọsin gbogbo, ibaa jẹ ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi ko gbọdo gba ju idaji iye ero ti wọn ti maa n gba tẹlẹ lọ, bẹẹ ni ko gbọdọ si ikorajọ eeyan to ju aadọta lọ nibikibi.

Ṣugbọn ọrọ ti Lai Mohammed sọ yii ti n mu kawọn eeyan fibinu fesi loriṣiiriṣii, wọn ni ṣe nijọba fẹẹ maa da awọn riboribo ni, ati pe ko si iṣọkan ninu awọn alaṣẹ pẹlu bi ikede ọtọọtọ ṣe n waye latọdọ ijọba apapọ.

Leave a Reply