Ẹ ma dan an wo! Ẹ ma mu Sunday Igboho o

Ẹ ma dan an wo! Ẹ ma mu Sunday Igboho o

Lati ibi gbogbo ni orilẹ-ede Naijiria nibi, ati nibi ti awọn ọmọ Yoruba wa kari aye, ni wọn ti n pariwo soke lala bayii pe ijọba apapọ Naijria, labẹ Ọgagun Muhammadu Buhari, ko gbọdọ mu Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni ti gbogbo eeyan n pe ni Sunday Igboho. Wọn ni ki wọn ma dan an wo rara ni.

Ohun to fa idi ariwo bayii ko ju mimu ti awọn agbofinro mu olori awon ọmọ Biafra, Nnamdi Kanu. Ọjo Aiku, Sannde to kọja yii, ni wọn mu Kanu, ṣugbọn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana, ni wọn too kede faye pe awọn ti mu un, ko si sẹni to mọ ibi ti wọn gbe e pamọ si tẹlẹ tabi iru iya ti wọn ti fi jẹ ẹ. Bi wọn ti kede pe awọn ti mu un naa ni wọn gbe e lọ sile ẹjọ, nibi ti Adajọ Binta Nyako ti ni ki awọn DSS tete maa mu un lọ, ki wọn lọọ ti i mọle sọdọ wọn titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje.

NIdii eyi, ọpọ ọmọ Yoruba ni ọkan wọn ko soke, nitori wọn nigbagbọ pe ijọba yii le ṣe iru ohun ti wọn ṣe fun Kanu yii fun Sunday Igboho naa, nigba to jẹ iru ariwo kan naa ni wọn jọ n pa, bo tilẹ jẹ pe ọna ti kalukku gbe tirẹ gba yatọ sira wọn. Ohun ti Nnamdi Kanu n pariwo ni pe ki gbogob ọmọ Ibo pata kuro ni Naijiria, ki wọn si ni orilẹ-ede tiwọn ti yoo maa jẹ Biafra. Ohun ti Igboho naa si n pariwo ni ki Yoruba kuro labẹ ijọba Naijiria, ti awọn naa yoo si ni orilẹ-ede wọn ti wọn yoo maa pe ni Yoruba Nation.

Nigba to si jẹ ohun kan naa ni Kanu ati Igboho n sọ, to jẹ bi ijọba Naijiria ti koriira Kanu naa ni wọn koriira Igboho, iyẹn lawọn ọmọ Naijiria ṣe bẹrẹ ariwo lori ẹrọ ayelujara: ni Facebook ni o, ni Twitter, ni Instagram, ati nibi gbogbo to ku pata ni wọn ti n sọ ọ kiri, ti awọn mi-in si n leri pe wahala gidi ni yoo ṣẹlẹ bi ọlọpaa tabi DSS kan ba ni oun yoo mu Igboho. Ṣe awọn ọlọpaa ti gbiyanju rẹ, bẹẹ ni awọn agbofin ro mi-in ti ẹni kan ko mọ, lati mu Igboho yii, ṣugbọn pabo lo ja si fun wọn.

Loootọ ni Sunday Igboho n ṣe iwọde kaakiri lori  ọrọ yii, ṣugbọn lasiko to ti n ṣewọde tirẹ, ẹni kan ko ku ri, bẹẹ ni ko si jagidijagan, yatọ si ti ilẹ Ibo nibi ti Kanu ti n dari wọn to jẹ ojoojumọ loku n sun lori ọrọ yii. Igboho ati awọn eeyan rẹ ti kede tẹlẹ pe awọn yoo wa ni Eko lọjọ Satide to n bọ yii, boya kinni naa yoo ṣii ṣee ṣe pẹlu eyi to ṣẹlẹ yii, tabi ko ni i ṣee ṣe mọ, afi ti awọn adari eto naa ba kede lọwọ ara wọn.

 

Leave a Reply