Ẹ ma gbero pe ki Naijiria pin, ka wa niṣọkan lo daa- Alake ilẹ Ẹgba

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, ti parọwa sawọn eeyan to n kigbe ipinya Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede pe ki wọn yee sọ bẹẹ, Kabiyesi sọ pe iṣọkan nikan lo le mu alaafia ba wa.

Nigba ti ikọ onimọto RTEAN nipinlẹ Ogun, ti Alaaji Akibu Efele jẹ alaga wọn, ṣabẹwo si Alake laafin ẹ lọsẹ to kọja yii lati sami ayẹyẹ ọdun kan Efele lọfiisi ni Alake parọwa yii l’Abẹokuta.

Ọba naa sọ pe Naijiria ko tun gbọdọ koju ogun abẹle kankan mọ, nitori ipinya yii ko le mu nnkan mi-in wa ju ogun lọ.

O fi kun un pe bi a ba pinya, yoo sọ wa di ajoji lorilẹ-ede mi-in, orilẹ-ede wo ni yoo si gba eeyan to le ni miliọnu igba ataabọ (250m) lalejo. Kabiyesi sọ pe ko le ju ọjọ meji lọ tawọn eeyan Naijiria yoo fi jẹ gbogbo ounjẹ ilu naa tan, iyẹn lo ṣe jẹ pe ka tete gba ara wa bi Ọlọrun ṣe to wa pọ lo daa ju, ki Yoruba ma pinya, ki Ibo ma sọ pe awọn n lọ si Biafra, kawọn Hausa naa ma si gbe Arewa bori Naijiria to so gbogbo wa pọ.

Bi Naijiria ba kuna gẹgẹ bii orilẹ-ede, Alake sọ pe gbogbo iran eeyan dudu lo kuna yẹn.

Arọwa ti Kabiyesi pa yii, ta ko ikede ti ajijagbara Yoruba nni, Sunday Igboho, ṣe laipẹ yii pe idasilẹ orilẹ-ede Yoruba lo kan bayii, ati pe kawọn ọmọ Yoruba to wa nilẹ Hausa tete maa bọ nile.

Ohun ti Alake tẹpẹlẹ mọ ni pe ifọwọsowọpọ gbogbo ẹya Naijiria, lai wo ti ẹsin ati ede lo daa fun orilẹ-ede yii, ki i ṣe ipinya rara.

Leave a Reply