“Ẹ MA JẸ KAWỌN ỌMỌLEEWE WỌLE O, Ẹ JẸ KO D’ỌDUN TO N BỌ”

Ẹgbẹ awon olukọ ni yunifasiti gbogbo nilẹ yii ti wọn n pe ni ASUU ti sọ pe awọn fara mọ igbesẹ ijọba apapọ pe ki awọn ọmọleewe gbogbo ma ti i wọle, lati kawe tabi ṣedanwo oniwee mẹwaa (WAEC) ọdun yii, nitori arun korona to wa lode. Ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ to n bọ yii ni idanwo naa iba bẹrẹ, bo ba jẹ awọn ọmọ Naijiria fẹẹ kopa ninu ẹ.

Awọn olukọ ileeewe giga julọ yii ni ki awọn ijọba Naijiria farawe awọn orile-ede Afrika mi-in bii Kenya, nibi ti wọn ti ni awọn ko ni i ṣi ileewe awọn titi di ọdun 2021. Wọn ni bi ijọba tiwa naa ba ṣe bẹẹ ko buru rara, nitori yoo fun wọn ni anfaani lati le mura daadaa fun wiwọle awọn  ọmọ wọnyi, ti ko fi ni i si bi ajakalẹ arun korona yii yoo ṣe mu wọn.

Ileeṣẹ to n ṣeto ẹkọ fun ijọba apapọ ti n pade pẹlu awọn to n ṣeto idanwo WAEC, ọna bi wọn yoo si ti ṣe e ti wọn yoo ṣi awọn ileewe yii pada, ki awọn ọmọ ti wọn fẹẹ ṣedanwo oniwee mẹwaa yii le ri i ṣe ni wọn n ṣe. Ṣugbọn Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ yunifasiti yii, Ọjọgbọn Biọdun Ogunyẹmi, sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin Sunday Punch pe ko si ijọba gidi kan to fẹran awọn eeyan rẹ ti yoo jẹ ki wọn ṣi ileewe lasiko yii, afi to ba ṣe pe awọn obi ti wọn n pariwo pe ki awọn ọmọ wọn pada sileewe yii le tọwọ bọwe adehun pe ohun yoowu to ba ṣelẹ sawọn ọmọ wọn awọn lawọn fa a, awọn ko si ni i mu ẹnikẹni si i.

Ogunyẹmi ni “Ẹyin naa ẹ wo o, Kenya ti ni awọn ko ni i ṣi ileewe awọn titi ọdun to n bo, 2021; ṣe awọn naa ko ni idanwo ti wọn fẹẹ ṣe ni! Ṣugbọn aabo ẹmi lo ja ju. Bo ba jẹ ka ti ileewe titi ọdun to n bọ ni ko ni i jẹ ka padanu ọpọlọpọ awọn ọmọ wa, deede ni.

“Bo ba jẹ iyẹn ni yoo din iku ku lawujọ wa, ko si ohun to buru bi Naijiria ba ṣe bẹẹ. Bi ẹmi ba wa, ireti n bẹ, ẹni to ba wa laye lo n lọ si yunifasiti. Ṣe awọn yunifasiti ti wọn fẹe tori ẹ ṣedanwo tiẹ ti i ṣe tan lati bẹrẹ iṣẹ ni!” Bẹẹ ni Ọjọgbọn Ogunyẹmi wi.

Leave a Reply