“Ẹ ma jẹ ki Buhari lọ sọsibitu niluu Oyinbo mọ o” 

Aderounmu Kazeem

Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba ti wọn n ṣayẹwo eto iṣuna owo fun ọdun 2021 ti sọ pe o ṣe pataki ki awọn oṣiṣẹ to n ba Aarẹ Muhammed Buhari ṣiṣẹ ri i pe baba naa ko lo siluu oyinbo lati lọọ gba itọju kankan mọ.

Loni-in, Ọjọbọ, Tọsidee, ni igbimọ awọn aṣofin naa sọrọ yii nigba ti akọwe agba fun ọfiisi Aarẹ, Tijani Umar, yọju lati sọrọ nipa eto iṣuna owo fun ọfiisi Aarẹ fọdun 2021. O waa ṣalaye iye owo ti awọn yoo na lọdọ Aarẹ nikan, ati ọna ti awọn fẹẹ na owo naa si ni.

Nibi to ti n ṣalaye ni alaga igbimọ ọhun, Sẹnetọ Danjuma La’ah, ti fi i lọkan balẹ wi pe awọn yoo fọwọ si owo ti wọn fẹẹ na ọhun, ṣugbọn o ṣe pataki ki wọn tọju ileewosan to wa ni ọfiisi Aarẹ daadaa. Idi ni pe bii biliọnu meji owo Naira ni wọn kọ pe awọn fẹẹ na si ọsibitu to wa ninu Aṣo Rock yii, fun ọdun to n bọ yii nikan.

O ni, awon ko tun fẹẹ gbọ ọ mọ wi pe wọn n sare gbe Aarẹ Muhammed Buhari, tabi ẹnikẹni ninu awọn oṣiṣẹ ẹ lọ soke okun fun itọju mọ.

Nigba ti akọwe agba naa si pade awọn oniroyin lẹyin to kuro niwaju awọn igbimọ to bi i leere ọrọ, ohun to sọ fun wọn ni pe oun yoo gbiyanju lati tun ileewosan ọhun ṣe, eyi ti yoo fun Buhari lanfaani lati maa ri i lo, dipo ti wọn yoo ṣe tun maa  sare gbe e lọ soke okun fun itọju.

 

Leave a Reply