‘Ẹ ma ko awọn ọdaran ọrọ SARS wa sọgba ẹwọn wa o

Aderounmu Kazeem

Eeyan bii igba lawọn ọgba ẹwọn kaakiri ipinlẹ Eko ti kọ bayii lati gba sọdọ ni kete ti ile-ẹjọ ti paṣẹ ki wọn lọọ fi wọn pamọ sawọn ọgba ẹwọn naa.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan bii igba ni ileeṣẹ ọlọpaa ko lọ sile ẹjọ bayii lori ẹsun idaluru, latari rogbodiyan lori ọrọ awọn ọlọpaa SARS to waye lọsẹ to kọja

Bi wọn ti ko wọn debẹ ni ile-ẹjọ ti ni ki wọn lọọ fi wọn pamọ naa si ọgba ẹwọn, ti wọn yoo si maa ti ibẹ waa jẹjọ. Ṣugbọn niṣe lawọn ọgba ẹwọn kọ lati gba wọn sọdọ, ni wọn ti da wọn pada si teṣan awọn ọlọpaa ti wọn mu wọn si tẹlẹ.

Ninu alaye ti Muyiwa Adejọbi, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, ṣe lo ti sọ pe loootọ lawọn ti ko igba ninu awọn ẹni afurasi bii okoolelẹẹdẹgbẹta (520) tọwọ te lasiko wahala SARS yii lọ sile ẹjọ.

Ọkunrin ọlọpaa yii fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe ọgba ẹwọn lo yẹ ki igba eeyan tawọn ti foju wọn ba ile-ẹjo yii wa, ṣugbọn wọn ko gba wọn wọle nibẹ, nitori wọn ni lati ṣayẹwọ arun koronafairọọsi fun wọn. O fi kun un pe eyi ti ko ba ni in lara nikan ni wọn le gba lọgba ẹwọn.

O ni kaakiri agọ ọlọpaa lawọn le pin awọn eeyan ọhun si bayii, niwọn igba ti awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn ko ti i gba wọn wọle.

Ọgbẹni Rotimi Ọladokun, agbẹnusọ fun awọn ọgba ẹwọn l’Ekoo, sọ pe loootọ lawọn ko gba awọn eeyan bii igba ọhun sawọn ọgba ẹwọn nitori wọn ni lati ṣe ayẹwọ fun wọn, ki wọn si fidi ẹ mulẹ wi pe arun koronafairọọsi ko ṣe wọn. O ni nigba yẹn gan-an lawọn too le da wọn pọ mọ awọn to wa lọdọ awọn tẹlẹ.

O ni eyikeyii ti esi ayẹwo ba fidi ẹ mulẹ wi pe o ni in lara, lojuẹṣẹ nijọba yoo mu un sọdọ, ti ara ẹ ba si ti ya ni wọn yoo da a pada sọdọ awọn, nibi ti yoo ti maa lọọ jẹjọ ẹ, titi ti ile-ẹjọ yoo fi ṣẹdajọ to yẹ lori ọrọ rẹ.

Leave a Reply