‘Ẹ ma kọrukọ wa sabẹ awọn oniṣegun ibilẹ o, ẹsin ibilẹ ni tiwa’

Gbenga Amos, Abẹokuta

Awọn ẹlẹsin ibilẹ ti fi aidunnu wọn han si igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ogun fẹẹ gbe lati forukọ wọn silẹ labẹ awọn oniṣegun ibilẹ, ki ijọba le maa ri si igbokegbodo wọn, awọn ẹlẹsin naa lawọn o ki i ṣe oniṣegun ibilẹ rara, wọn ni ẹsin abalaye ni tawọn, awọn si lominira lati ṣe ẹsin to ba wu awọn.
Ọrọ yii jẹ yọ nibi ipade pataki kan tawọn ẹlẹsin abalaye, paapaa awọn onigunnuko nipinlẹ Ogun, ṣe laarin ọsẹ yii niluu Abẹokuta.
Oloye Ọdunayọ Ọsanyintolu to gbẹnu sọ fawọn oniṣẹṣe naa sọ pe ọrọ ikilọ yii ṣe pataki lasiko yii latari awuyewuye to ti n jẹ yọ lori igbesẹ ijọba ipinlẹ Ogun lati forukọ awọn oniṣegun ibilẹ silẹ labẹ ofin, ti wọn si ni kawọn ẹlẹsin naa lọọ forukọ wọn silẹ gẹgẹ bii oniṣegun ibilẹ.
Ọsanyintolu, Sinaba Igunnuko ti ipinlẹ Ogun, sọ pe awọn o ni i gba kijọba ko awọn ni papa mọra lati ṣe iforukọsilẹ naa, nitori akere ko jọ kọnkọ, ẹsin abalaye, ẹsin ibilẹ ni eyi tawọn n ṣe, gẹgẹ bi awọn ẹsin yooku ṣe wa, awọn ki i ṣe oniṣegun ibilẹ rara.
O tun rọ ijọba Gomina Dapọ Abiọdun lati ma ṣe jẹ kawọn ti wọn ko mọ ọtun yatọ si osi nipa ẹsin ibilẹ gba a lamọran to le ṣakoba fun iṣejọba rere rẹ, o ni ẹgbẹ onigunnuko abalaye, eyi ti Oloye Dauda Adejọla n dari nikan ni ẹgbẹ ẹlẹsin abalaye to fidi mulẹ, o lawọn kan ti wọn fẹẹ dupo ni wọn n pe ara wọn ni ohun ti wọn ko jẹ.
Ni ipari, Ọsanyintolu ṣalaye pe ẹgbẹ awọn ki i dupo ọba, awọn o si ki i fi iṣegun ibilẹ ṣiṣẹ ṣe, tori ẹsin abalaye lawọn yan laayo, oun lawọn si n ṣe.

Leave a Reply