Ẹ ma polongo saa kẹta fun mi, mo n lọ ni 2023- Buhari

Adefunkẹ Adebiyi

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023, ko ni i le ọjọ kan si i ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo fi kuro nipo olori orilẹ-ede yii, gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe fẹnu ara ẹ sọ eyi niluu Mẹka, ni Saudi Arabia, lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2021.

Yatọ si eyi, Aarẹ tun kilọ fawọn onipolongo ibo isọnu to ni wọn n ba oun kede pe koun tun lọ lẹẹkan si i, o ni ki wọn ma ṣe polongo ibo kankan foun rara, nitori ọdun 2023 loun yoo fipo aarẹ Naijiria silẹ toun yoo ba toun lọ.

Ninu atẹjade kan ti wọn pe akọle ẹ ni “Aarẹ Buhari sọ pe oun yoo fipo silẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023” ni wọn ti fi ero ọkan Buhari yii han sode.  Garba Sheu ti i ṣe amugbalẹgbẹẹ Aarẹ lori iroyin ati ikede lo si buwọ luwe ọhun.

Ninu abala kan atẹjade naa, o wa nibẹ ti wọn ni Buhari sọ pe, “ Mo fi Kurani mimọ bura, pe pẹlu ilana ofin ni mo maa sinlu, n o si fipo silẹ nigba ti saa mi ba tan.

“Mi o fẹ kẹnikẹni maa sọrọ nipa saa kẹta tabi afikun saa fun mi, mi o ni i gba iyẹn”

Nipa imọ ẹrọ to wọ eto idibo bayii, eyi teeyan le fi ẹrọ kọmputa dibo, Buhari sọ pe ohun to daa ni. O ni ai ti i si ẹrọ naa nigba toun lo fa a ti wọn fi yi ibo oun lẹẹmẹta ti wọn ni oun ko wọle ibo. O ni pẹlu imọ ẹrọ to de yii, akoyawọ yoo maa wa ninu ibo didi daadaa.

O waa ni laarin oṣu mejidinlogun to ku toun yoo fi ṣe aarẹ Naijiria yii, gbogbo ohun toun ba le ṣe lati mu aye awọn ọmọ Naijiria daa si i loun yoo ṣe koun too lọ.

Bakan naa ni Buhari sọ pe kawọn eeyan tiẹ maa foju ire wo iṣakoso oun yii naa kẹ, ki wọn yee fi gbogbo igba bu ẹnu atẹ lu u pe oun ko ṣe daadaa.

O ni ṣe awọn to n sọ pe oun ko wulo yii le fi eto aabo Ariwa-Ila Oorun ati ti Guusu-Guusu orilẹ-ede yii lasiko yii we bo ṣe wa ni 2015. Buhari sọ pe iyatọ gidi lo ti wa ninu eto aabo igba naa si eyi to n lọ lọwọ lasiko toun yii.

  Ninu atẹjade yii, apa kan naa tun wa nibẹ ti wọn ni Aarẹ ti sọ pe, “Iṣoro ti mo ni naa ni apa Ariwa Iwọ-Oorun (North West), nibi tawọn eeyan ti n para wọn, ti wọn tun n ji nnkan ara wọn. Mo ni lati fi ọwọ lile mu wọn ni, bẹẹ ni mo si maa maa fọwọ lile mu wọn lọ titi digba ta a ba ri wọn pe pada, ti wọn ko ṣe ara wọn lohun mọ.”

Bi ọrọ ti Buhari sọ yii ṣe bọ sori ayelujara lawọn eeyan ti bẹrẹ si i fi ero ọkan wọn han, wọn n powe a n ri were sa, o ni ti wọn ba de oke odo ki wọn duro de oun.

Ọpọ eeyan loju opo Fesibuuku ni wọn sọ pe ta ni Buhari ṣẹṣẹ n sọ fun pe oun n lọ ni 2023, wọn ni ẹni to jẹ pe bii ko loun o ṣe mọ bayii ko si maa kangara rẹ lọ lori lara gbogbo ilu, to waa n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ, to n sọ pe awọn kan n polongo saa kẹta foun.

Wọn ni ai ri ọrọ sọ lo n daamu Buhari atawọn eeyan ẹ, nitori were eeyan ni yoo polongo ibo fun wọn lẹẹkan si i.

 

Leave a Reply