Stephen Ajagbe, Ilorin
Bawọn Musulumi jake-jado orilẹ-ede Naijiria ati lagbaaye ṣe n mura ọdun Itunu aawẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti ṣekilọ fawọn oloṣelu atawọn alatilẹyin wọn, to fi mọ awọn to fẹẹ lo anfaani naa lati da ilu ru, lati ma sọ ibudo ikirun Yidi di agbo oṣelu.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Lawal Bagega, lo ṣekilọ naa ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Ajayi Ọkasanmi, gbe sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Bagega ki gbogbo Musulumi ku agbaja aawẹ Ramadan, o fi da wọn loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo pese aabo to peye fun wọn lasiko ayẹyẹ ọdun naa.
Bẹẹ lo ni awọn agbofinro yoo fiya to ba tọ jẹ ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iwa dida ilu ru, paapaa awọn kan to n gbero lati fa wahala ni Yidi lọjọ ọdun.
Ileeṣẹ yii ti waa gbe awọn ofin kan jade lati ka awọn to n gbero bẹẹ lọwọ ko.
Lara awọn ofin naa ni pe ko gbọdọ si omi inu ọra tawọn eeyan mọ si piọ-wọta nibi ti wọn ti maa kirun, nitori pe wọn ti pese omi ti wọn fi maa ṣe aluwala sibẹ.
Yatọ si eyi, ọlọpaa tun fofin de kikan sara sawọn oloṣelu tabi pipolongo ẹgbẹ oṣelu kan nibudo naa.
Bakan naa, o ṣekilọ fawọn awakọ ero lati ṣọra ṣe, ki wọn si maa ro tawọn to n fẹsẹ rin mọ tiwọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa waa ni araalu le pe sori awọn nọmba yii, 08126275046 ; 07032069501, ti wọn ba kẹẹfin awọn afurasi oniwa ọdaran tabi ti irin wọn ko mọ.