Ọrẹoluwa Adedeji
Oludamọran pataki lori eto iroyin fun igbimọ ipolongo ibo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu, Dele Alake, ti rọ awọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour, iyẹn Alaaji Atiku Abubakar ati Peter Obi, lati tọ ọna alaafia lori abajade eto ibo yii. O ni pẹlu bo ṣe jẹ pe esi idibo naa yoo ti tẹ wọn lọwọ bayii lati ọdọ awọn aṣoju ẹgbẹ koowa wọn, ki wọn ṣe bi Jonathan, iyẹn aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, ti ṣe lọdun 2015, ki wọn pe Aṣiwaju Tinubu, ki wọn ki i ku oriire pe oun lo wọle ibo aarẹ to waye lọjọ Satide.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo sọrọ yii nibi ipade oniroyin kan to ṣe niluu Abuja. Alake ni, ‘‘Lọdun 2015, INEC ko duro ki alaga ajọ eleto idibo kede esi idibo naa tan to fi pe Aarẹ Muhammadu Buhari, to si ki i ku oriire, ni ilana ifẹ ati ajọṣe ti ijọba awa-ara-wa pe fun.
O waa rọ Atiku Abubakar ati Peter Obi lati tẹle igbesẹ yii kan naa, dipo ti wọn yoo maa sọrọ to le da ogun tabi wahala silẹ. Alake ni ohun to ti daa ju lọ ni ki awọn oludije mejeeji funpo aarẹ yii pe Tinubu bayii bayii, ki wọn si ki i ku oriire.