Monisọla Saka
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni oṣerebinrin ilẹ wa nni, Kẹmi Afọlabi, kede faye pe oun ti bẹrẹ itọju lori aisan alagbara kan ti wọn n pe ni Lupus to n ba oun wọya ija.
Lori Instagraamu rẹ lo gbe fọto to ya ni ọsibitu to ti n gba itọju naa si to si sọ ọ di mimọ pe oun ti bẹrẹ itọju arun Lupus to n ṣe oun nileewosan ‘The John Hopkins Hospital, to wa ni Maryland, lorilẹ-ede Amẹrika.
Kẹmi ni, “Mo ti bẹrẹ itọju aisan Lupus mi lonii, ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, nileewosan Hopkins medicine, Aliamdulillahi.
Awọn oninuure, oloju aanu kan ni wọn jẹ ki eleyii ṣee ṣe. Ọlọrun a bukun fun gbogbo yin. Ẹ maa fi adura ran mi lọwọ”.
Ninu oṣu Karun-un ọdun yii ni awọn ẹlẹgbẹ Kẹmi Afọlabi kan nidii iṣẹ tiata ṣeto ikowojọ fun itọju aisan to n koju rẹ ọhun.
Nitori eyi lo fi jẹ pe, nigba to n dupẹ, o darukọ awọn bii Mercy Aigbe, Funkẹ Akindele-Bello (Jenifa), Toyin Abraham, Yọmi Fabiyi, Akin Ọlaiya, Adeoti Kazim to jẹ ọkọ Mercy Aigbe tuntun, Ṣọla Kosọkọ, Wumi Toriọla, Folukẹ Daramọla atawọn mi-in lati fi ẹmi imoore rẹ han fun eto ikowojọ ti wọn fi ṣe iranlọwọ fun un.
Laipẹ yii ti Kẹmi pariwo ohun to n ṣe e sita lawuyewuye kan n lọ lori afẹfẹ pe ọmọbinrin naa lọ si ṣọọṣi to gbajumọ kan nilẹ yii fun iwosan arun to n ṣe e yii.
Ṣugbọn Kẹmi Afọlabi jẹ ko di mimọ pe Musulumi ododo loun, bẹẹ ni oun ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu Allah, ati pe awọn ti ko rikan ṣekan lo n gbe ọrọ naa kiri, kawọn ololufẹ oun gẹ fila ma-wobẹ, kí wọn ma ṣe ka ọrọ naa si.
O ni, lati igba ti iroyin aigbadun oun ti di ohun ti gbogbo aye mọ si loun ti n gbọ oriṣiiriṣii iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n sọ nipa oun.
Kẹmi Afọlabi kuku waa pana ọrọ naa pe oun ko figba kan lọ sile ijọsin fun iwosan, ki ẹnikẹni to ba ri oun nibẹ jade sita ko waa wi.
O ni koda gan-an toun ba tilẹ lọ si ṣọọṣi, ṣebi Ọlọrun naa ni wọn ni wọn n pe nibẹ, ṣugbọn ki wọn ma ṣe gbọ ti awọn ẹlẹgan pẹlu bo ṣe jẹ pe oun ko nilo ẹnikẹni lati ba oun bẹ Ọlọrun oun.
Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kẹta, ọdun ta a wa yii ni arẹwa obinrin naa kegbajare sita lori aisan to n ba a finra, to si ti di agbaana fun un, pe awọn dokita ni ọdun marun-un pere lo ku foun lati lo loke eepẹ.
Latigba naa ni awọn ololufẹ rẹ ti n sare kiri lati ri i pe o gba itọju to yẹ niluu oyinbo, ki alaafia le ba a to o lara.