‘Ẹ maa too dohun igbagbe ninu itan Yoruba pẹlu bẹ ẹ ṣe kọyin sohun tawọn eeyan yin fẹ’

Adefunke Adebiyi 

 Ọkan ninu awọn ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba ni ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘Apapọ O’odua Kọya (AOKỌYA).

 Awọn ni wọn binu tan ninu atẹjade ti wọn fi sita laipẹ yii, nibi ti wọn ti sọrọ buruku sawọn gomina ilẹ Yoruba nipa ki Naijiria ma pin tawọn eeyan naa fara mọ. AOKỌYA ni gomina mẹfa pere ko le gba ẹnu ọgọrin miliọnu ọmọ Yoruba sọrọ nipa ohun ti wọn fẹ, wọn ni wọn o ni i awọn eeyan naa yoo too di nnkan igbagbe ninu itan Yoruba, ti wọn yoo parẹ patapata.

 Ọrọ ti wọn sọ yii ko deede waye, ipade kan tawọn olori ẹgbẹ APC nilẹ Yoruba pe lọjọ Sannde to kọja yii, nile ijọba to wa ni Marina, lo fa a. Nibi ipade naa ti gomina Eko, Ọṣun, Ogun pẹlu Aṣiwaju Bọla Tinubu, Oloye Bisi Akande atawọn mi-in wa ni wọn ti sọ pe awọn ko fara mọ idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba, wọn ni ki Naijiria wa niṣọkan lo daa.

 Eyi ni AOKỌYA n fesi si ninu atẹjade wọn, ti wọn fi sọ pe ko jọ awọn loju pe awọn gomina yii sọ iru ọrọ bẹẹ jade. Wọn ni eru lọpọ gomina fi depo ti wọn wa, wọn debẹ tan, wọn n nawo ilu lai da ileeṣẹ ẹyọ kan ṣoṣo bayii silẹ.

 AOKỌYA sọ pe owo ilu lawọn gomina yii n na, ounjẹ ọfẹ ni wọn n jẹ pẹlu mọlẹbi wọn, itọju ọfẹ ni wọn n gba nileewosan, owo olowo ni eegun n na, aṣọ alaṣọ lọga wọn si n da bora.

 Ẹgbẹ yii sọ pe ṣebi ọrọ awọn Fulani to n daamu ilu, ti wọn n ji awọn eeyan gbe, ti wọn tun n fẹran jẹko wa nibẹ, awọn gomina ti wọn pe ara wọn laṣaaju ilu yii ko ri nnkan kan sọ si i, niṣe ni wọn dakẹ ti wọn ṣe bii pe ohun gbogbo n lọ bo ṣe yẹ.

 Won lo ba ni lọkan jẹ, pe ọṣu karun-un yii to pe ọdun mẹrinlelọgbọn ti Awolọwọ ti ku lawọn gomina  n sọ iru ọrọ yii nipa Yoruba. Bẹẹ, lati ọdun 1999 ti awọn alagbada yii ti n ṣejọba, ko sẹni to ri ohun ti Awolọwọ fi ọdun meje pere ṣe ninu wọn ṣe.

 Bẹẹ, ogun ọdun tiwọn ree ti wọn ti n ṣe kinni ọhun bọ.

 AOKỌYA fi kun un pe ohun to n ṣẹlẹ nilẹ Yoruba yii ko ye awọn gomina, nitori wọn ki i ṣe gomina ilẹ Yoruba, gomina APC ni wọn. Wọn ni to ba ye wọn ni, ija ominira Yoruba ni wọn ko ba maa ja, ki i ṣe ki wọn maa tẹle Buhari to fẹẹ ta Naijiria fawọn Fulani ẹgbẹ rẹ.

 Ṣa, AOKỌYA lawọn gomina yii ko too gba ẹnu Yoruba sọrọ, wọn ni nitori wọn ko nigbagbọ ninu ohun ti Yoruba fẹ.

 Ẹ oo ranti ti Gomina Kayọde Fayẹmi, Ṣeyi Makinde ati Rotimi Akeredolu ko si nibi ipade ọjọ Sannde naa.

Leave a Reply