Ẹ pada sinu ẹgbẹ APC, Lai Muhammed rọ awọn alatilẹyin rẹ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Minisita to n ri si ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Muhammed, ti rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ alatilẹyin rẹ ti wọn n fapa jẹnu, ti wọn ya danu kuro ninu ẹgbẹ naa lati pada si APC nipinlẹ Kwara, o ni kikuro ninu ẹgbẹ kọ ni ọna abayọ to kan.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni minisita naa sọrọ ọhun, o ni gbogbo gbọn-mi-si-i, omi-o to-o to n ba ẹgbẹ naa finra ni yoo yanju ko too di ọdun 2023 ti idibo gbogbogboo yoo waye. O tẹsiwaju pe iroyin ti kan oun lara latori ẹrọ ayelujara pe ọpọ awọn alatilẹyin oun ni wọn ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, ti wọn si ti dara pọ mọ SDP.

Lai Mohammed, ni oun gẹgẹ bii ẹni kan to ti jiṣẹ-jiya lati ri i pe ẹgbẹ oṣelu APC di igi alọye nipinlẹ Kwara, ko ṣee ṣe koun fi ẹgbẹ naa silẹ lọ si ẹgbẹ mi-in. O ni bo tilẹ jẹ pe ẹtọ wọn ni wọn n ja fun, sibẹ, ki wọn maa fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ. Gbogbo ohun to n run ni yoo tan nilẹ ko too di ọdun 2023.

Leave a Reply