Faith Adebọla
Olori ẹsin Musulumi kan to n ṣaaju mọṣalaṣi Ẹsiteeti tawọn aṣofin apapọ n gbe, Apo Legislative Quarters, Sheikh Muhammadu Khalid, ti sọ pe ọrọ iṣakoso to wa lode yii ti kọja gbigbadura fun, o ni fifakoko ṣofo lo jẹ teeyan ba loun n gbadura funjọba Muhammadu Buhari yii, tori adura ko ran ọrọ ijọba yii mọ, afi teeyan ba fẹẹ purọ.
Ninu waasi kan tolori ẹsin naa ṣe nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide opin ọsẹ yii, lo ti sọrọ ọhun, o ni ijakulẹ nla ni Buhari mu ba awọn eeyan to dibo fun un lọdun mẹfa sẹyin, o ni ohun ti wọn reti kọ ni wọn ba, ati pe ko sidii lati maa gbadura fun ijọba yii mọ tori to ba jẹ adura maa tun nnkan ṣe ni, o yẹ ki ojo adura tawọn eeyan n gba latọjọ yii ti mu ayipada rere wa, ṣugbọn ti ko siyatọ rere kan.
Sheikh Khalid ni: “Ẹsin mi kọ wa pe ka jẹ olododo, mo si gbọdọ jẹ bẹẹ. Ootọ ọrọ ko ni ka ma sọ oun, ti mo ba le la ootọ ọrọ mọlẹ lasiko iṣejọba Aarẹ Goodluck Jonathan ana, a jẹ pe alagabagebe ẹda ni mi niyẹn ti mi o ba le sọrọ lasiko yii, nitori ẹsin tabi ẹya to papọ.
“Ina gidi la fi n ṣere lorileede yii, ipakupa ati ifẹmiṣofo to n waye lorileede yii ti fẹẹ di nnkan mi-in mọ wa lọwọ bayii tori ojoojumọ lo n ṣẹlẹ.
Lasiko ijọba to lọ, ipinlẹ meloo kan lawọn Boko Haram ti n yọ wọn lẹnu, ṣugbọn ẹ sọ fun mi, ipinlẹ meloo lo le fọwọ sọya bayii pe eto aabo awọn ṣi feeyan lọkan balẹ daadaa? Ko si.
Ṣe adura waa ni ko to ni, ṣe adura ti mu iyatọ kankan wa? Ẹ saa jẹ ki Buhari da Naijiria pada si ipo to ti ba a nigba to de. Awọn kan le ma nifẹẹ si ọrọ ti mọ sọ yii tori iwe igbeluu meji ni wọn ni ni tiwọn, ṣugbọn ko sẹni ti ko mọ ninu ọkan rẹ lọhun pe nnkan ti buru balumọ gidi lasiko iṣejọba yii o”