Ẹ sọ fun Tinubu ko ma fakoko ẹ ṣofo lati dije pẹlu Atiku – Babangida

Faith Adebọla

Bo ba jẹ imọran ti eekan ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, Alaaji Babangida Aliyu, gba Aṣiwaju Bọla Tinubu, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, lo fẹẹ tẹle ni, wọn ti gba a lamọran pe ko ma ṣopo loun n da ara oun laamu pe oun n dije lọdun 2023, tori fifi akoko ati owo ṣofo ni.
Babangida Aliyu to ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Niger fọdun mẹjọ, lo sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa yii, pe to ba jẹ Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni APC fa kalẹ ni, oun ni iba daa ju lọ gẹgẹ bii aarẹ tori o ti ni iriri ati ẹkọ lati ṣakoso daadaa.
Nigba to n sọrọ lori eto tẹlifiṣan Channels kan, Aliyu ni:
“Ọrẹ mi atata ni Bọla Tinubu, mi o ro pe o yẹ ko fi akoko ẹ ṣofo lasiko yii, mo si ro pe o yẹ ko na owo sori nnkan mi-in, iba dara to ba ṣagbatẹru fun oludije to kere lọjọ-ori. O le mu Gomina Ekiti, Kayọde Fayẹmi, tabi ko wa awọn mi-in ti ko dagba to o, ko si ti wọn lẹyin lati jawe olubori, tori ko si ohun ti Tinubu le ni lọkan lati ṣe fun Naijiria ti iru awọn ta a n sọ yii ko ni i ṣe.
“Bi Tinubu ṣe fi itara sọrọ l’Abẹokuta lọjọsi yẹn, mi o ro pe ẹnikan le sọ ni Naijiria lode oni, pẹlu eeyan bii miliọnu lọna igba (200 million) pe ‘emi lo kan’. Ki i ṣe oun lo kan, koda to ba tiẹ fẹẹ sọ pe awọn eeyan oun lo kan, ka sọ ọ lọna bẹẹ, pẹlu gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ ati oriṣiiriṣii ẹya to wa ni Naijiria, ti awọn eeyan agbegbe Ariwa/Ila-Oorun, Aarin-Gbungbun Ariwa ati Guusu/Ila-Oorun ko ti i bọ sipo aarẹ ri ni Naijiria, awọn eeyan agbegbe wọnyi lo yẹ ki wọn sọ pe awọn lo kan, ki i ṣe Tinubu. Tori o ti ṣeranwọ fawọn eeyan ko tumọ si pe oun lo kan, ko si iwe adehun kankan lori iyẹn, ko si akọsilẹ kan to fihan pe lagbaja kan lo kan.
“To ba jẹ Tinubu lo kan ninu ẹgbẹ APC wọn, wahala tiẹ niyẹn, ki i ṣe wahala ọmọ Naijiria. Awọn ọmọ Naijiria maa jade waa pinnu ẹni to wu wọn ju lọ, pẹlu ohun toju wọn ti ri.”
Bẹẹ ni Babangida Aliyu sọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: