Ẹ tun ero yin pa lori fifofin de ọkada gigun lorileede Naijiria – Oluwoo

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Nitori ipinnu ijọba apapọ lati fofin de ọkada gigun kaakiri orileede yii, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Oluwoo ti ilu Iwo, ti ke si ijọba, labẹ Aarẹ Muhammed Buhari, lati tun ero rẹ pa lori eyi.

Oluwoo sọ pe erongba naa jẹ ọta awọn araalu, o si da bii bibu iyọ soju egbo ni. Dipo ki wọn fagi le e, Ọba Akanbi ni ṣe lo yẹ kijọba wa ọna imọ-ẹrọ ti wọn yoo gba lati maa ṣakoso gigun ọkada.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, fi sita, lo ti sọ pe loootọ ni ọkada gigun jẹ ipenija to lagbara fun eto aabo orileede yii, sibẹ, fifi opin si gigun rẹ yoo tun mu ki iwa idigunjale ati iwa janduku gbilẹ si i.

Ọba Akanbi fi kun ọrọ rẹ pe airiṣẹ ṣe yoo pọ si i lorileede yii tijọba ba le fofin de gigun ọkada, eleyii ti ewu rẹ si pọ ju anfaani to wa nidii rẹ lọ.

O ni ọkada lọpọlọpọ, paapaa, ni awọn agbegbe ti mọto ko lanfaani lati de, fifi ofin de e yoo mu inira ba awọn araalu ju eyi ti wọn n dojukọ lọwọ bayii lọ.

O gba ijọba apapọ niyanju lati maa ṣakoso iṣẹ ọkada gigun, ki eto iforukọsilẹ wa fun awọn ojulowo ọlọkada lati tete mọ igba ti awọn ọdaran ba dara pọ mọ wọn.

Bakan naa ni Oluwoo rọ awọn ọlọkada lati gbe iwa ọmọluabi wọ nigba gbogbo, nipasẹ bẹẹ, yoo ran awọn oṣiṣẹ alaabo lọwọ lati mu awọn kọlọransi laarin wọn.

O ni eto-aabo orileede yii mẹhẹ pupọ. Tijọba ba si fẹẹ fopin si iwakiwa, wọn gbọdọ ṣagbeyẹwo igbesẹ ti wọn ba fẹẹ gbe daadaa. Airiṣẹ ṣe yoo kun wahala eto aabo lọwọ tijọba ba le fofin de ọkada gigun.

Oluwoo ke si gbogbo awọn araalu lati jẹ ojulalakan-fi-n-ṣọri bayii pẹlu bi eto aabo ko ṣe wu ni lori mọ, ki wọn si maa fura si gbogbo irin ajeji layiika wọn.

Leave a Reply