Ẹ wo Adeṣina to fipa ba iya ọgọta ọdun lo pọ n’Idanyin

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Adeṣina Adebọwale lorukọ ọkunrin yii, ẹni ogoji ọdun ni. Ọjọ Sannde ọsẹ yii ti i ṣe ogunjọ, oṣu kẹfa, lo wọle iya ẹni ọgọta ọdun (60), o si ba iya naa lo pọ karakara n’Idanyin, nitosi Agbara, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun.

Ọmọ iya to ba sun naa lo mu iya rẹ lẹyin lọ si teṣan ọlọpaa Idayin lọjọ naa, to ṣalaye fun wọn pe oju iya oun ma ri eemọ lọsan-an gangan o.

Ọmọ iya ti wọn forukọ bo laṣiiri naa ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ni lọjọ Sannde naa, nigba ti iya ẹni ọgọta ọdun naa wa ninu ile rẹ, Adeṣina yii gba ọna ẹburu wọle, o si fipa ba iya oun lo pọ.

CSP Ọlayinka Kuyẹ,  DPO teṣan Idanyin, da awọn ọtẹlẹmuyẹ sita lati dọdẹ ẹni to ba iya agbalagba bẹẹ sun, wọn si pada ri Adeṣina Adebọwale mu.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, to fiṣẹlẹ naa ṣọwọ s’ALAROYE, sọ pe Adeṣina ko parọ, o ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun wọle iya agbalagba naa, oun si ba a sun gidi loootọ.

Niṣe ni wọn mu iya lọ sọsibitu fun itọju, ti wọn si gbe Adeṣina lọ sẹka itọpinpin iwa ọdaran, nibi ti yoo gba dele-ẹjọ laipẹ rara.

Leave a Reply