Ẹ wo Adekọla, ọmọọdun mẹwaa lo fipa ba lo pọ, lo ba ni kawọn obi rẹ ma binu

Faith Adebọla

Igbadun iṣẹju diẹ, ahamọ ọlọjọ gbọọrọ, ni baale ile ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Adekọla Adeṣina, wa bayii, latari ẹsun pe o ki ọmọ aladuugbo ẹ kan mọlẹ, ọmọọdun mẹwaa pere, o si fipa ṣe ‘kinni’ fọmọbinrin ọhun, o ṣe e yankan-yankan.

SP Josephine Adeh, ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja, olu-ilu ilẹ wa lo fọrọ yii lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, ninu atẹjade kan.

Adeh ni obinrin kan, Rose Solomon, lo mẹjọ wa si teṣan ọlọpaa Abuja, pe ki wọn ba oun wadii afurasi ọdaran yii. O lawọn jọ n gbe adugbo kan naa ninu Ẹsiteeti Prince and Princess, to wa l’Abuja ni, amọ oun fura si i, iṣesi ẹ pẹlu ọmọ oun, Faith Solomon, ọmọọdun mẹwaa, mu ifura lọwọ, iwa ọmọ naa ti yatọ lẹnu ọjọ mẹta yii, o si jọ pe nẹbọ oun yii ti n fọbẹ ẹyin jẹ awọn niṣu.

Eyi lo mu ki Kọmiṣanna ọlọpaa Abuja, CP Sadiq Abubakar, yan awọn ọmọọṣẹ ẹ kan tẹle obinrin naa, wọn si lọọ gbe afurasi ọhun lati wadii ohun to ṣẹlẹ, lẹyin ti wọn ti fọgbọn beere ọrọ lọwọ ọmọbinirin kekere ti wọn sọrọ ẹ ọhun.

Adeh ni iyalẹnu lo jẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ nigba ti afurasi yii jẹwọ pe loootọ loun dẹṣẹ ti wọn fẹsun ẹ kan oun naa, o ni iṣẹ eṣu ni, ki wọn foriji oun, ki wọn si ba oun bẹ iya ọmọdebinrin ọhun.

Kia ni wọn ti da a duro sahaamọ to wa lati tubọ ṣewadii ibi tọrọ naa ti kan eṣu to darukọ, ati bo ṣe rin in to fi jẹ ọmọọdun mẹwaa, lo ri ki mọlẹ.

Bakan naa ni wọn ti gbe ọmọbinrin ọhun lọ fun ayẹwo ati itọju iṣegun lọsibitu ijọba kan ti wọn ko darukọ.

Alukoro ni iwadii ṣi n tẹsiwaju. O ni laipẹ lawọn maa wọ afurasi naa dewaju adajọ, nibi ti yoo ti raaye ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Leave a Reply