Ẹ wo Ajibọla, orukọ ṣọja lo fi lu ọpọ eeyan ni jibiti ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Yooba bọ, wọn ni ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni toloun, ọwọ ajọ NSCDC, ẹka tipinlẹ Kwara, ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji (42) kan, Abdulsalam Ajibọla, fẹsun pe o n pe ara rẹ ni ṣọja, to si n lu awọn eniyan ni jibiti.

Agbẹnusọ ajọ NSCDC ni Kwara, Ọgbẹni Ayẹni Ọlasunkanmi, lo fiṣẹlẹ ọhun lede ninu atẹjade kan to tẹ Alaroye lọwọ lọjọ Aje, Mande, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin yii. Ayẹni ni afurasi Abọlaji lo pe ara rẹ ni ṣọja, to si lu awọn ọmọ Naijiria ni jibiti nipasẹ gbigba owo lọwọ wọn, to si n sọ pe oun yoo ba wọn ṣe e ti wọn yoo fi ri ileewe ọmọ ogun (Nigeria Defence Academy) NDA, to wa niluu Kaduna wọ, to si n gba owo lọwọ wọn.

Ayẹni sọ pe Ajibọla, ti gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira (700,000), lọwọ arakunrin kan, Abdullahi Saheed, bakan naa ni lo tun gba ẹgbẹrun lọna mẹrinlọgọrun-un Naira (#96,000), lọwọ Rọpo Gabriel, to fi wọn lọkan balẹ pe wọn aa ri ileewe (NDA), wọ.

Wọn ni gba ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Picnic kan lọwọ Wolii Samuel Olugbemiga, to ni oun yoo maa ba wolii fi ṣe kabu-kabu (ọkọ èrò), sugbọn to gbe ọkọ naa sa lọ.

Oke-Onígbìn, nijọba ibilẹ Ìsin, nipinlẹ Kwara, lọwọ ti tẹ afurasi naa, Ayẹni ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii wọn aa foju afurasi naa ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply