Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Akanji Oluwaṣeyi ni baba ti ẹ n wo yii n jẹ, ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) ni. Ẹka to n ri si ifipaba ọmọde lo pọ nipinlẹ Ogun lo wa bayii, nitori ọmọ ẹ obinrin ọmọ ọdun mẹtala, ti wọn lo fipa ba lo pọ ni.
Ọmọ Akanji lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ọbantoko, l’Abẹokuta, lọgbọnjọ, oṣu kejila to kọja yii, pe baba oun wa si ṣọọbu toun ti n kọṣẹ telọ lọjọ yii, o bẹ ọga oun pe ko jẹ koun wale lati pọn omi fun oun nile, ọga si yọnda oun lati lọọ jiṣẹ naa.
Ọmọbìnrin yii sọ fawọn ọlọpaa pe oun lọọ pọnmi fun baba oun loootọ, ṣugbọn boun ṣe pọnmi naa tan lo ra oun mu, o si fipa ba oun lo pọ.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti sọ pe ohun ti ọmọde naa sọ ni teṣan ọlọpaa Ọbantoko yii lo mu DPO ibẹ, CSP Sunday Ọpẹbiyi, ko awọn eeyan rẹ lẹyin lọ sile Akanji Oluwaṣeyi, nibi ti wọn ti fọwọ ofin mu un.
Alukoro ṣalaye pe niṣe l’Akanji kọkọ yari pe ko sohun to jọ bẹẹ, oun ko ba ọmọ oun lo pọ o.
O ni ṣugbọn nigba ti ọmọ bibi inu ẹ naa sọ ọ ko o loju pe o ba oun lo pọ loootọ, ko yee purọ, baba naa ko le wi nnkan kan mọ, niṣe lọrọ pesijẹ.
Ileewosan kan ti wọn n pe ni Olukọya ni wọn sare mu ọmọ ọdun mẹtala naa lọ fun itọju, bi wọn ṣe taari baba rẹ sẹka to n wadii awọn to n ṣe ọmọde niṣekuṣe.