Ẹ wo awọn adigunjale mẹrin tọwọ tẹ l’Alakukọ

Faith Adebọla, Eko

 Ahamọ ọlọpaa lawọn afurasi ọdaran mẹrin kan, Micheal Mustapha, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Suleiman Babajide ati Ọlalekan Adeṣina, ti wọn jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Gideon Daniel, ẹni ọdun mẹtalelogun ti wọn ni adigunjale paraku ni wọn, agbegbe Alakukọ, AMJE, Mọṣalaaṣi, nipinlẹ Eko, titi de Dalemọ, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti n ṣọṣẹ ni tiwọn.

Nnkan bii aago mejila oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọwọ ba awọn mẹrẹẹrin.

Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Olumuyiwa Adejọbi, fi ṣọwọ s’ALAROYE nipa iṣẹlẹ naa sọ pe ibọn ilewọ kan, ọta ibọn ti wọn o ti i yin, ada ati ọbẹ lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ awọn afurasi naa.

Adejọbi ni ọpẹlọpẹ awọn fijilante atawọn olugbe kan ti wọn n ṣe iṣẹ ojulalakan fi n sọri lalaalẹ lo jẹ kọwọ awọn agbofinro tete tẹ awọn kọlọransi ẹda yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn tete fi awọn mẹrẹẹrin ṣọwọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ CID to wa ni Panti, ni Yaba, fun iṣẹ iwadii.

Lẹyin iwadii lawọn afurasi naa maa balẹ sile-ẹjọ lati foju wina ofin.

 

Leave a Reply