Ẹ wo Baalẹ to n ba ọmọ bibi inu ẹ sun l’Owode-Yewa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lẹyin ọdun kẹrin to ti n ba ọmọ bibi inu ẹ to jẹ obinrin sun, aṣiri Baalẹ Oose Agbẹdu Ajibawo, l’Owode Yewa, Rasheed Sholabi, ti tu bayii, awọn ọlọpaa ti mu un.

Ọmọ rẹ ti wọn lo n ba sun naa lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Owode-Ẹgbado. O ṣalaye fun wọn pe ọmọ ọdun mọkanla pere loun wa ti baba oun ti n ba oun lo pọ, ọmọ naa ni titi dasiko yii toun pe ọdun mẹẹẹdogun lo ṣi n ba oun ṣe ere egele.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe ọmọ naa ṣalaye pe oun ti ni iṣoro lati tọ latari ibasun ti baba oun tete ṣiju oun si naa, bẹẹ, oun ko ribi kan sa lọ, nitori iya oun ti ku nigba toun ko ti i ju ọmọ ọdun meji pere lọ, oun ko si mọ ẹbi rẹ kankan, Baalẹ ko jẹ.

Ifisun yii lo jẹ ki wọn lọọ mu Baalẹ, lo ba yari pe oun kọ o. Ọkan ninu awọn iyawo rẹ to ti kọ ọ silẹ lo yọju si teṣan naa, to si kin ọrọ ọmọ Baalẹ lẹyin.  Obinrin naa sọ pe oun ti ka Baalẹ mọbi to ti n ba ọmọ rẹ sun ri, ohun to jẹ koun kuro nile rẹ titi doni niyẹn.

Wọn tiẹ ni niṣe ni Baalẹ daku rangbọndan nigba ti iyawo to ta ko o yii n sọrọ, n ni wọn ba sare gbe e lọ sọsibitu fun itọju.

Ọga ọlọpaa Ogun, CP Edward Ajogun ti ni ki wọn gbe e lọ sẹka to n ri si ifiyajẹ ọmọde ati lilo wọn nilokulo.

Leave a Reply