Ẹ wo Deji atawọn ikọ rẹ ti wọn n digunjale l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Nnkan ayọ nla lo jẹ fawọn eeyan ilu Akurẹ ati agbegbe rẹ fun bọwọ awọn agbofinro ṣe pada tẹ awọn ikọ adigunjale ẹlẹni mẹrin to ti n yọ awọn araalu lẹnu lati bii ọdun meji sẹyin.

Awọn afurasi ọhun, Deji Ajayi ati Babajide Adewọle ti wọn jẹ ọmọ ọdun mejilelogun, Dare Adeoye, ẹni ọdun mẹrinlelogun pẹlu Banjọ Adu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn la gbọ pe wọn wa nidii bi wọn ṣe yinbọn pa oṣiṣẹ banki kan Nọfisat Adetutu Ibrahim, ẹni ti wọn pa sinu ṣọọbu POS rẹ lagbegbe Oke-Ọgba ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2019.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun ta a wa yii, ni wọn lawọn ogbologboo adigunjale naa tun lọọ ba wọn lalejo ojiji laduugbo Owe-Akala, Oke-Aro, l’Akurẹ, nibi ti wọn tun ti ja ọkunrin oni POS mi-in lole, ti wọn si tun yinbọn lu u laya lẹyin ti wọn gbowo ọwọ rẹ tan.

Laipẹ yii lawọn ọlọdẹ mẹta tun kagbako iku ojiji lasiko ti awọn ikọ adigunjale naa lọọ pa itu ọwọ wọn lawọn ileepo kan to wa lagbegbe Ọda ati iyana Custom, nigboro Akurẹ.

Olori ikọ adigunjale ẹlẹni mẹrin ọhun, Dare Adeoye,  ṣalaye fun wa nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo pe igbo loun n ta tẹlẹ ki oun too bẹrẹ iṣẹ adigunjale.

O ni ko ti i pẹ rara ti oun ṣẹṣẹ n kuro lọgba ẹwọn ti wọn ran oun lọ lori ẹsun  idigunjale nigba tọwọ tun pada tẹ oun atawọn mẹta mi-in ti awọn jọ n ṣọsẹ.

Ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun jẹwọ pe loootọ lawọn n digunjale, ti awọn si n paayan, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe awọn ti wọn pa naa lawọn mọ nipa rẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, ni awọn ti pari gbogbo igbesẹ to yẹ lati foju awọn janduku tọwọ tẹ ọhun ba ile-ẹjọ lati lọọ foju wina ofin.

 

 

 

 

 

Leave a Reply