Ẹ wo Gbenga, ọkan ninu awọn adigunjale to ja ọkọ bọọsi awọn ọmọ ileewe gba l’Ọba-Ile

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ adigunjale to ja bọọsi awọn ọmọ ileewe kan gba lagbegbe Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, ni nnkan bii oṣu meji sẹyin, Ọmọyajowo Gbenga, lọwọ awọn agbofinro pada tẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ to kọja.

Aarọ kutukutu, ni nnkan bii aago mẹfa idaji lawọn adigunjale ọhun da dẹrẹba bọọsi naa lọna lasiko to ṣẹṣẹ fẹẹ maa gbe awọn akẹkọọ lọ sile-iwe ninu ẹsiteeti to wa l’Ọba-Ile.

Ọna Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, la gbọ pe wọn gbe ọkọ yii sa lọ, ti ko si sẹni to tun gbọ ohunkohun nipa rẹ mọ lati igba naa.

Ọsẹ to kọja ni ikọ awọn adigunjale yii kan naa tun ṣọṣẹ mi-in niwaju Chiken Republic, to wa lagbegbe Ọlọkọ, Road block, niluu Akurẹ, nibi ti wọn ti ja ọkọ Hummer bọọsi tuntun kan ti wọn fi n kiri burẹdi gba pẹlu ibọn.

Ọna ilu Ibadan ni wọn lawọn ẹruuku ọhun tun kọri si ni kete ti wọn ja ọkọ ọhun gba tan, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i fi bẹẹ rin jinna ti ọkọ naa fi wọgbo mọ wọn lọwọ latari ere asapajude ti wọn n sa nigba tawọn ọlọpaa n le wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, ni o to bii ọgbọn iṣẹju tawọn ogboju ọlọsa ọhun atawọn agbofinro fi doju ibọn kọ ara wọn ki ọwọ too pada tẹ Gbenga nikan nigba tawọn yooku rẹ raaye sa mọ wọn lọwọ.

O ni iwadii awọn si n tẹsiwaju lati ṣawari awọn adigunjale yooku pẹlu ọkọ ile-iwe ti wọn kọkọ ja gba lọjọsi nibikibi ti wọn ba ta a si.

Leave a Reply