Ẹ wo Isiwat, nitori ẹgbẹrun marun-un naira lo ṣe ṣa ọmọ ọdun mejila ladaa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Abẹrẹ sọnu, wọn lọọ bu Ṣango, lowe to ba iyaale ile kan,  Isiwat Taofeek, mu. Obinrin ẹni ogoji ọdun naa ni awọn ọlọpaa mu laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lagbegbe Isọka, Kugba, l’Abẹokuta. Wọn lo yọ ada si ọmọ odun mejila to n gbe lọdọ ẹ, bẹẹ lo fi ọbẹ gbigbona jo o lara kaakiri nitori ẹgbẹrun marun-un naira to ni oun tọju pamọ, ọmọ naa lo si ko o.

Ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ni awọn ọlọpaa teṣan Adatan lọọ mu Isiwa nile, lẹyin ti obinrin kan to jẹ ayalegbe pẹlu ẹ mu ọmọ ti apa oriṣiiriṣii wa lara rẹ naa wa si teṣan yii, to si sọ fun wọn pe obinrin naa lo ṣe ọmọ ọdun mejila ọhun yankan yankan bẹẹ.

Nibi to ti n fẹjọ sun lọwọ lọmọdekunrin naa ti ṣubu lulẹ, lo ba daku lọ gbari. Ileewosan ni wọn sare gbe e lọ lati teṣan naa fun itọju.

Kia ni DPO Samuel Aladegoroye ti ran awọn ikọ rẹ lati lọọ mu  Isiwa ti wọn fẹsun kan wa, nigba to de lo ni ọmọ aburo ọkọ oun lọmọ yii, o ti ṣe diẹ to ti n gbe pẹlu oun.

O loun tọju ẹgbẹrun marun-un naira sinu ile, oun ko si ri owo naa mọ, oun si gbagbọ pe ọmọ yii lo ji i, ohun to jẹ koun da sẹria fun un niyẹn pẹlu fifi ọbẹ sina, toun jẹ ko gbona daadaa koun too fi jo o ni gbogbo ara. Ko sọ nipa ti ada ti araale rẹ ni o fi ṣa a.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi sọ pe ọga awọn, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn gbe Isiwa lọ sẹka to n ri si ifiyajẹ ọmọde, nibi ti wọn yoo ti wadii rẹ daadaa fun iwa to hu naa.

 

Leave a Reply