Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Rexlawson Johnson, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn(31) ni ọkunrin ti ẹ n wo yii, awọn ọlọpaa teṣan Ibafo lo mu un lọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, lẹyin to pa ọrẹbinrin ẹ ti wọn jọ lọ sotẹẹli kan ti wọn n pe ni Mọlayọ Hotel, nitori ọrọ to ṣe bii ọrọ laarin wọn.
Ko sẹni to mọ pe Johnson, ọmọ ipinlẹ Ebonyi, ti yọ jade ninu otẹẹli naa lẹyin to pitu ọhun tan, asiko ti awọn olotẹẹli n yẹ yara wo ni wọn de ibi ti oun ati ọrẹbinrin ẹ, Patricia John, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) jọ lo, ni wọn ba ba ọmọbinrin naa nilẹẹlẹ pẹlu apa nibi ọrun rẹ, ko si jọ ẹni ti ẹmi wa lara rẹ mọ rara.
Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣe wi, maneja otẹẹli yii, Adebayọ Aladeṣuyi, lo sare lọọ sọ fun wọn ni teṣan ọlọpaa Ibafo pe awọn ba oku obinrin kan ni yara, awọn ko si ri ọkunrin ti wọn jọ wọ yara oun mọ.
Eyi ni DPO teṣan naa, CSP Jide Joshua, ṣe ko awọn ọtẹlẹmuyẹ lẹyin lọ si otẹẹli yii, awọn ni wọn gbe oku Patricia lọ si ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ ni Ṣagamu, fun ayẹwo.
Lẹyin eyi lawọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii abẹnu, wọn si pada mọ pe Johnson ni ẹni naa to gbe oloogbe Patricia lọ si otẹẹli, to sa lọ lẹyin tobinrin naa jade laye.
Wọn ṣọ ọ titi, wọn si ri i mu, nigba ti wọn si fọrọ wa a lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ loun gbe Patricia lọ si otẹẹli yii, ọrọ kan lo dija laarin awọn to fi di pe awọn wọya ija.
Johnson ni nibi tawọn ti n ja ni oloogbe ti ṣubu lulẹ, bo ṣe ku niyẹn. O ni ohun to jẹ koun sa lọ lai jẹ ki ẹnikẹni mọ ninu otẹẹli ọhun niyẹn.
Ẹka to n gbọ ẹsun ipaniyan ni CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn gbe ọkunrin yii lọ fun itẹsiwaju iwadii, ati ki wọn le gbe e lọ sile-ẹjọ. Bẹẹ lo rọ awọn olotẹẹli pe ki wọn ri i daju pe wọn n ṣe akọsilẹ awọn eeyan to ba waa ṣe faaji nibẹ, nitori iṣẹlẹ bii eyi le waye, ohun to ba wa lakọsilẹ naa lawọn yoo fi dọdẹ ẹni to ba ṣiṣẹ ibi.