Ẹ wo olukọ Covenant University to fipa ba ọmọ ọdun mẹtadinlogun lo pọ l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

 

Fun pe o fipa ba ọmọbinrin tọjọ ori ẹ ko ju mẹtadinlogun (17) lọ lo pọ, ọlọpaa ti mu olukọ Yunifasiti Covenant to wa niluu Ọta, iyẹn Ọmọwe Stephen Ukenna.

Ọjọ kọkanla, oṣu kẹta yii, lọwọ ba lẹkiṣọra yii, iyẹn lẹ́yìn tawọn obi ọmọ to fipa ba lo pọ̀ lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ọta, pe Stephen, ẹni ọdun mọkanlelogoji, (41) fipa ba ọmọ awọn sun.

Ọmọbinrin naa pe awọn obi rẹ lori foonu lọjọ naa ni lati ileewe to wa, o ṣalaye fun wọn pe lẹkiṣọra yii pe oun si ọfiisi rẹ, o loun fẹẹ ṣeto ijọloju kan fun ọrẹ ọmọ yii to fẹẹ ṣọjọọbi.

Ki wọn le jọ ṣeto naa lo ṣe pe ọmọ ọdun mẹtadinlogun yii si ọfiisi rẹ, iyẹn ko si mọ pe olukọ naa ni ero mi-in lọkan.

Afi bi ọmọ ṣe wọle tan ti olukọ tilẹkun mọ ọn, to si fipa ba a lo pọ lori tabili to wa ninu ọfiisi naa. Bo ṣe ṣe e tan lọmọ sọ ohun to ṣẹlẹ fawọn obi ẹ, n lawọn ba lọọ fẹjọ sun ọlọpaa.

Ọkunrin yii jẹwọ pe oun ba ọmọbinrin ọhun sun, ṣugbọn ko le sọ idi kan pato to fi ṣe e.

Wọn ti gbe e lọ sẹka iwadii iwa ọ̀daràn, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun ṣe wı

 

Leave a Reply