Ẹ wo Pasitọ Shobọwale to fipa ba ọmọ ọdun mẹtadinlogun lo pọ n’Ifọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iwadii to lọọrin gidi ti bẹrẹ bayii lori ọkunrin yii, Pasitọ Tayọ Shobọwalẹ, ti sọọṣi Kerubu ati Serafu Oke-Igbala, n’Ifọ, ipinlẹ Ogun, nitori wọn lo fipa ba ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) kan sun ninu awọn ọmọ ijọ rẹ ninu oṣu kẹta to pari yii.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita ṣalaye pe ọmọbinrin tawọn forukọ bo laṣiiri naa ati iya rẹ ni wọn mẹjọ lọ si ẹka to n gbọ ọrọ mọlẹbi ni kọmandi ọlọpaa to wa l’Ọta, ti wọn ṣalaye ohun  to ṣẹlẹ gan-an.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa ṣalaye pe Pasitọ Tayọ lo ni koun wa si ṣọọṣi lọjọ naa fun adura, oun si lọ. O ni nigba toun debẹ lo di pe oun ati pasitọ nikan lawọn wa nibẹ, iyẹn naa lo si ṣe ni anfaani lati fipa ba oun laṣepọ, to ba oun sun karakara.

Lẹyin ibalopọ ipa naa, ọmọ naa sọ pe Pasitọ Tayọ paṣẹ foun pe koun wẹ iwẹ kan ninu ṣọọṣi naa. Abẹla kan ti pasitọ ti ṣiṣẹ si lo ni koun fi pa gbogbo ara oun kari, latigba naa lo ni oun ti ko si wahala, to jẹ niṣe loun yoo deede ṣubu lulẹ, toun ko ni i mọ ibi toun wa mọ, toun yoo si wa bẹẹ fun ọpọlọpọ wakati ki oun too lalaafia pada.

Ohun tọmọ wi yii lo mu Eeria kọmanda Ọta, ACP Muhideen Obe, ran awọn ọmọọṣẹ rẹ lati lọọ mu Pasitọ Tayọ Shobọwale wa.

Pasitọ naa ko kọkọ jẹwọ bi wọn ti wi, wọn ni niṣe lo sẹ kanlẹ pe oun ko ṣe ohun to jọ bẹẹ. Ṣugbọn nigba ti wọn mu ọmọbinrin naa jade si i, ti oju wọn ko oju, pasitọ ko le purọ mọ, o si ṣoro fun un lati wẹ ara rẹ mọ ninu ẹsun ti wọn fi kan an.

Bayii ni CP Edward Ajogun

Leave a Reply