Ẹ wo Tunde, awakọ to fipa ba obinrin lo pọ ni Mowe, to tun gbowo nla lọwọ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Tunde Bello lọkunrin ti ẹ n wo yii n jẹ, ẹni ọdun mejilelọgbọn to n ṣiṣẹ awakọ lagbegbe Mowe ni. Oun lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun gbe ọmọbinrin kan lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, oun fipa ba a lo pọ, oun si gba ẹgbẹrun lọna ogoje naira (140,000) lọwọ ẹ pẹlu.

Ọmọbinrin tawọn ọlọpaa forukọ bo laṣiiri naa lo kọkọ lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Mowe, pe nigba toun n lọ sibi iṣẹ nidaaji kutu ọjọ naa loun wọ mọto ayọkẹlẹ ti Bello jẹ awakọ rẹ.

O ni agbegbe Ogunrun loun ti wọ ọ, ṣugbọn nigba tawọn de iyana Mowe, awakọ yi ọwọ ọkọ pada, niṣe lo dari ọkọ sọna Ibadan, lo ba wa mọto naa wọnu igbo, nibi to ti fẹrẹ lu oun pa ko too fipa ba oun lo pọ.

Yatọ si ifipabanilopọ yii, obinrin naa sọ pe niṣe ni Tunde tun ni oun ko ni i jẹ koun kuro ninu igbo naa, afi toun ba pe awọn ẹbi oun, ti wọn si fi ẹgbẹrun lọna ogoje naira ranṣẹ.

O ni bayii loun pe bọọda oun, tiyẹn si fowo naa ranṣẹ si akanti oun, ẹsẹkẹsẹ naa loun si fowo ohun ranṣẹ si asunwọn ti dẹrẹba yii ni koun fi si. Lẹyin naa lo too yọnda oun lati maa lọ.

 

Lati ọjọ naa lawọn ọlọpaa ti n wa ọkunrin yii, ki wọn too ri i mu lọjọ kẹrìndínlógún, oṣu kin-in-ni yii. Nigba ti wọn si beere lọwọ ẹ pe ṣe loootọ lo huwa ọhun, Tunde Bello jẹwọ pe loootọ ni.

Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn taari ẹ sẹka to n gbọ ẹsun ijinigbe, ibẹ naa lo si wa bayii to n gbeju gbere.

Leave a Reply