Ẹ wo Usman, foto ihooho obinrin lo fi n lu awọn eeyan ni jibiti lori intanẹẹti

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọdaran ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Usman Muhammed, to n fi foto ihooho obinrin lu awọn ọkunrin ni jibiti lori ẹrọ ayelujara, nile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin ti paṣẹ pe ko lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Adajọ Sikiru Oyinloye lo paṣẹ naa nigba ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC, nipinlẹ Kwara, wọ ọ lọ sile-ẹjọ laarin ọsẹ yii.

Usman ni wọn fẹsun kan pe o lo ayederu orukọ; Adepeju Ọmọlara, lati maa fi lu awọn ọkunrin ni jibiti.

Akọsilẹ ajọ EFCC ṣalaye pe inu oṣu keji, ọdun 2020, lọwọ tẹ Usman niluu Ilọrin, ti wọn si ba awọn atẹjiṣẹ to fi n ba oriṣiiriṣii ọkunrin sọrọ ifẹ lori ikanni ibanidọrẹẹ, Facebook ati Whatsapp, eyi to fi tan wọn to si n gba owo lọwọ wọn.

Oṣiṣẹ EFCC, Adenikẹ Ayoku, ni ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, lọwọ ti tẹ ọdaran onijibiti naa. O tẹsiwaju pe Usman tun maa n gbe foto ihooho obinrin sori ikanni to fi n ba awọn ọkunrin sọrọ, to si fi n gba owo.

Ọdaran naa loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ Oyinloye ni ki wọn gba awọn foonu mejeeji to lo fun iṣẹ jibiti rẹ lọwọ ẹ, ko si di ẹru ijọba.

Leave a Reply