Ẹ wo Victor Agunbiade, Ọmọ Yoruba to gbe orukọ Naijiria ga l’Amẹrika

Nibi ti awọn kan ti wa ti wọn ko ni iṣẹ meji ju ki wọn ba orukọ orilẹ-ede yii jẹ lẹyin odi lọ, awọn ọmọ ti a bi ninu ile-ire kan wa ti wọn ko wa ohun meji ju bi wọn yoo ṣe tun orukọ Naijiria ṣe lẹyin odi lọ. Ni ẹẹkọọkan ti iru eleyii ba ṣẹlẹ, inu ẹni a maa dun, bẹẹ ni ara ẹni a si maa ya gaga. Meloo meloo leeyan fẹẹ sọ ninu iwa buruku ti iroyin ẹ n jade lojoojumọ pe o n ti ọwọ awọn ọmọ Naijiria jade. Ṣe awọn ti wọn n gbe oogun oloro wọ ilu oyinbo ni gbogbo igba leeyan yoo wi ni, awọn ti wọn ko kọ iku ti kinni naa le mu dani, tabi awọn ti wọn n fi intanẹẹti lu jibiti, ti wọn si sọ ara wọn di ọmọ ‘yahoo-yahoo’ kari aye. Tawọn ti wọn n lu awọn obinrin oyinbo ni jibiti kari aye leeyan yoo wi ni, tabi ti awọn ti wọn n ko awọn ọmọ Naijiria ẹlẹgbẹ wọn mi-in lọ si awọn ilu oyinbo yii kan naa lati fi wọn ṣe aṣẹwo nibẹ.

Meloo leeyan tiẹ fẹẹ sọ. Tawọn ti wọn n gba ọna aṣalẹ, Sahara, wọ ilu oyinbo ni keeyan mẹnu le ni tabi ti awọn ti wọn n ba ọna oju-omi lọ, to si jẹ lẹyin ti wọn ba ti lakaka wọ awọn ilu yii tan, iṣẹ aburu ni wọn yoo maa gbebẹ ṣe. Ọrọ naa buru debii pe nibi yoowu ti wọn ba ti gbọ orukọ ọmọ Naijiria, wọn yoo maa wo wọn tifura-tifura, loju gbogbo aye bayii, onijibiti ati ole lọmọ Naijiria, bi wọn ba n bọ lọọọkan, ẹ tete tilẹkun yin ni. Ọrọ naa ko kan awọn ti wọn n ṣejọba wa, koda, tiwọn buru ju ti araalu lasan lọ, eyi ti wọn si ko ba wa ninu ka ba orukọ Naijiria jẹ lẹyin odi ni i jẹ oun. Tabi orilẹ-ede wo ni wọn ko ti n gbọ ti awọn aṣofin to n ko owo jẹ, ti awọn minisita ole, tabi ti olori orilẹ-ede to n ko owo Naijiria pamọ lọ sẹyin odi. Loootọ, wọn n ṣe bẹẹ lawọn orilẹ-ede mi-in, ṣugbọn ti Naijiria tiwa yii buru ju, nibi to jẹ mẹsan-an ninu mẹwaa eeyan to ba n ṣiṣẹ ijọba, igaara ọlọṣa, ole, akowo-ilu-jẹ ni wọn.

Agunbiade ninu aṣọ ologun Amẹrika

Oju buruku ti wọn fi n wo awọn ọmọ Naijiria yii lo mu ki ọrọ Victor Agunbiade, ọmọ ogun oju-omi l’Amẹrika kan, ya gbogbo aye lẹnu. Loootọ, ọmọ ogun oju omi l’Amẹrika ni, ṣugbọn ọmọ Naijiria ni, ọdun 2007 lo ko lọ sibẹ, ti wọn si ti ro pe ọkan ninu awọn ti ko sohun ti wọn ko le ṣe lati fi ri owo ni. Ọrọ Agunbiade ya aye lẹnu, ki i ṣe nitori pe ko si ẹlomiiran to le ṣe ohun to ṣe laye mọ ni, ṣugbọn nitori pe ọmọ Naijiria lo huwa bayii, ọmọ Naijiria lo ṣe ootọ bayii, ohun to mu iyanu naa wa gan-an niyẹn. Ọpọ eeyan niluu oyinbo ko gba, yatọ si awọn ti wọn ba ti ba awọn ọmọ Naijiria gidi rin nibẹ, pe ohun daadaa kan, tabi eeyan daadaa kan ti yoo ṣe ootọ, yoo jade lati inu awọn ọmọ Naijiria, nigba to jẹ oju onijibiti ni wọn fi n wo gbogbo ọmọ Naijiria ti wọn ba ri, nitori iroyin buruku ti wọn n gbọ lojoojumọ nipa wọn.

Nibi owo pinpin, nibi ti wọn ti n pin owo fun awọn ti wọn ba nilo rẹ fun iṣẹ ologun wọn, nibẹ ni wọn fi Agunbiade si, wọn si fi i ṣe olori apinwo fun awọn ọmọ ogun oju omi Amẹrika ti wọn wa ni Djibotti, latinu oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, titi di ibẹrẹ oṣu keje, 2020, ta a wa yii. Ohun  to waa ṣẹlẹ ni pe owo ti ọkunrin ọmọ Naijiria yii pin ki i ṣe owo kekere rara. Miliọnu marundinlaaadọta owo dọla ($45m) ni. Bi a ba ṣẹ owo naa si wẹwẹ lọdọ wa bayii, o sun mọ biliọnu mẹẹẹdogun naira. Ni Naijiria ti a wa yii, ọga ọlọpaa wo, ọga ṣọja wo, ọga iṣẹ ijọba Naijiria wo ni wọn yoo gbe iru owo bayii siwaju rẹ pe ko pin in ti nnkan ko ni i ṣe. Bawo ni yoo ti ṣe pin owo naa ti idaji ko ni i sọnu, tabi bii iko meji ninu ida mẹta owo na, iyẹn bii biliọnu mẹwaa ninu mẹẹẹdogun ko ni i sọnu, ti wọn yoo si ni ki awọn ti wọn ni owo naa gan-an maa pin eyi to ba ku mọ ara wọn lọwọ. Nibo ni wọn yoo ti ṣe iru rẹ ni Naijiria wa ti ọrọ naa ko ni i di ti EFCC nigbẹyin.

Ṣugbọn ijọba ati awọn olori ologun Amẹrika gbe owo to to bẹẹ kalẹ, bi a ba si da gbogbo owo ti wọn naa silẹ okeere fun ọrọ awọn ologun, owo naa ko iko meje ninu ida mẹwaa ni, wọn si fa gbogbo rẹ le Ọọfisa Victor Agunbiade lọwọ, wọn ni ko pin in bo ba ti fẹ, ko saa ri i pe oun ṣe eto naa bo ti tọ ati bo ṣe yẹ. Ohun to waa ya awọn ara Amẹrika yii lẹnu, iyẹn awọn ti wọn jẹ ọga pata fun Agunbiade, ni pe gbogbo owo naa lo pin, o si na an ni ọna ti awọn paapaa ko ro pe ẹnikan yoo ṣe bẹẹ na owo ijọba.  Ko si kọbọ kan to sọnu, tabi to ba ibi ti ko ṣee tọka si lọ, gbogbo owo na pata lo ni akọsilẹ, ko si si ibikan to na owo naa si ti ki i ṣe ibi ti awọn ti wọn gbe iṣẹ fun un fẹ ko na an si. Bo ti n na an lo n ṣe akọsilẹ rẹ, debii pe gbogbo owo ti wọn na naa, ko ṣoro fun ẹnikẹni lati mọ ibi ti wọn na an si ati ọjọ ti wọn na an.

Itumọ eleyii ni pe ninu gbogbo biliọnu mẹẹẹdogun ti wọn ko fun Agunbiade, kọbọ bayii ko yingin nibẹ, owo ijọba ti wọn fi ran an niṣẹ pe perepere. Ọrọ naa jọ awọn oyinbo yii loju debii pe wọn ni ko sohun ti awọn le ṣe ju ki awọn fi ami-ẹyẹ da Agunbiade lọla lọ, wọn si ṣe ayẹyẹ nla fun un ni Amẹrika nibẹ. Nibi ayẹyẹ yii ni awọn ọga rẹ ti n sọrọ loriṣiiriṣii nipa rẹ, awọn ni wọn si n sọ pe bi eeyan kan ba jẹ olododo, tabi ẹni to ṣee fọkan tan, paapaa bi ọrọ ba di ọrọ owo tabi ka fiiyan sipo aṣaaju, ko si ṣe aṣaaju naa daadaa, ọga ni ọmọ Amẹrika ti wọn n pe ni Victor Agunbiade. Bi ọrọ aye si ti ṣe ri niyẹn, wọn ko pe e ni ọmọ Naijiria nibẹ mọ, ọmọ Amẹrika ni wọn n pe e, wọn ti ri i bi ọkan ninu awọn ara wọn. Bẹẹ bo ba ṣe pe iwa aburu lo hu ni, koda ko ti lo ọgbọn ọdun nibẹ, ko tun jẹ ọmọ oniluu ju bẹẹ lọ, ọmọ Naijiria ni wọn yoo pe e.

Ẹkọ pataki ni ọrọ Agunbiade gbọdọ jẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria lẹyin odi. Pe ẹni to ba ru u re, yoo sọ ọ re. Ohunkohun ti eeyan ba hu niwa lẹyin odi ni yoo fi ibi to ti wa han, bo ba jẹ ileere lo ti jade tabi ile ti wọn ko ti raaye kọ ọ ni ẹkọ ile kankan, tabi ti wọn kọ oun naa, ti ko gbẹkọ. Agunbiade fi ẹkọ ijinlẹ iran Yoruba ati awọn agbalagba ọjọun ti wọn si maa fi n kọ awọn ọmọ wọn han, pe nibikibi ti wọn ba ti ba ara wọn, ki wọn ma jẹ ki iwa ọmọluabi kuro ninu ẹru wọn. Agunbiade fi iwa ọmọluabi han, iwa naa ko si ni i tan lọwọ rẹ, ohun ti yoo mu un ti yoo fi ṣiwa hu laarin awọn oyinbo ti wọn fẹran rẹ to bayii, Ọlọrun ko ni i jẹ ko ri i. Ki gbogbo ero to ba fẹẹ relu oyinbo fi ti Victor Agunbiade yii ṣe awokọṣe, nitori arikọṣe rere loun, ọmọ Naijiria to ṣee mu yangan lẹyin odi ni.

 

Leave a Reply