Ẹ woju awọn adigunjale ati babalawo wọn to n daamu awọn eeyan lAbẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣinkun lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ awọn adigunjale mẹrin kan ati babalawo wọn ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ja awọn eeyan Abẹokuta lole lọ, ki wọn si maa ko ipaya ba gbogbo eeyan.

Ọjọ kejilelogun oṣu keje yii lọwọ tẹ Dayọ Ajala, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) ti inagijẹ rẹ n jẹ Otege. Ismaila Badmus ti wọn tun n pe ni ‘Ọbasanjọ’ lo ṣikeji, Joseph Sunday, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) lo ṣikẹta, Chukwuemeka Paul lẹni kẹrin, nigba ti babalawo to n ṣaajo fun wọn ki wọn ma baa bọ sọwọ ọlọpaa ṣikarun-un, Okikiọla Adeṣina lorukọ ọkunrin naa, ẹni ọdun mẹrindilaaadọta (46) loun.

Awọn ọlọpaa SARS to n gbogun ti idigunjale ni olobo ta nipa awọn ole yii, pe ibi kan wa ti wọn maa n farapamọ si ni Ọdẹda. Eyi lawọn agbofinro naa fi tọpinpin wọn lọ sibẹ ti wọn si ri wọn mu. Mimu ti wọn mu wọn lo ṣatọna bi ọwọ ti tẹ babalawo wọn.

Okikiọla to jẹ babalawo yii ni awọn ole naa pe ni baba-nigbẹẹjọ. Wọn ni yatọ si pe o n ba awọn ṣoogun kọwọ ọlọpaa ma to awọn, oun naa lo tun maa n ṣe oro-igbaniwọle fawọn ole to ba ṣẹṣẹ dara pọ mọ awọn.

Ibọn ibilẹ ẹlẹnu meji, aake kan, ọbẹ meji atawọn oogun abẹnugọngọ lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.

Ọga Ọlọpaa agba, CP Edward Awolọwọ, ti ni ki iwadii to lagbara bẹrẹ lori wọn laipẹ rara.

Leave a Reply