Ẹ woju awọn ọdaran tọwọ tẹ l’Ekoo, oku ọrun lawọn maa n ja lole owo nla

Adefunkẹ Adebiyi

Awọn ti ẹ n wo fọto wọn yii, Osita Nwafor, Nwogu Joseph, Anthony Odama, Ikechukwu Nkem,James Okonkwo, Adedio Paulinus ati Ogundepo Olufẹmi, ki i lu jibiti owo kekere, miliọnu nla owo naira ati dọla ilẹ okeere ni wọn n wọ jade lakaunti awọn eeyan pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ banki, ọsẹ to kọja yii lọwọ ba wọn.

Awọn ọlọpaa RRS ipinlẹ Eko ni olobo ta lori iṣẹ ti wọn n ṣe. Iṣẹ ti wọn n ṣe naa ni pe wọn maa n tọpinpin awọn olowo ilu to ba doloogbe, wọn yoo kọwọ bọ akaunti wọn ni banki pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ ibẹ kan ti wọn jọ n ṣiṣẹ yii, wọn yoo si wọ miliọnu rẹpẹtẹ jade lakaunti naa, wọn yoo pin in laarin ara wọn.

Kọwọ too ba wọn yii, miliọnu mẹẹẹdọgbọn(25m) ni owo ti wọn fẹẹ wọ jade lapo asunwọn ẹnikan ninu awọn banki ilẹ yii, owo dọla ẹgbẹrun lọna igba ati ogun ($220,000) ni wọn si ti pari iṣẹ lori ẹ ni banki kan loke okun, ki wọn wọ ọ jade lo ku.

Aṣiri iṣẹ mejeeji yii lo tu sawọn ọlọpaa lọwọ ti wọn fi bẹrẹ si i dọdẹ awọn ikọ yii, olori wọn to n jẹ Osita Nwafor ni wọn kọkọ mu nibi kan niluu Eko, mimu ti wọn mu un lo ṣatọna bọwọ ṣe ba awọn yooku rẹ.

Osita ti wọn n pe ni Ossy ṣalaye pe ọdun 2019 loun ko awọn ikọ ole yii jọ, awọn ọmọọṣẹ oun naa si tun ni awọn ọmọọṣẹ tiwọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ owo olowo wiwọ jade ni banki yii.

O fi kun un pe siimu ti wọn fi n pe loun nilo ni toun, tọwọ oun ba tẹ siimu eeyan nla kan lawujọ, oun yoo ṣiṣẹ lori ẹ, awọn ọmọọṣẹ oun ni yoo pari iṣẹ yooku, bi wọn yoo ṣe wọ miliọnu jade tawọn yoo maa ṣe faaji awọn lọ niyẹn.

Wọn tiẹ ni James Okonkwo to jẹ ọrẹ Ossy tun ṣe gbaju-ẹ miliọnu mẹjọ fun ọga rẹ yii laipẹ yii, to jẹ bo ṣe wọ owo jade lo ko o sapo ni tiẹ, ọrọ ọhun ni wọn ṣi n fa lọwọ ti aṣiri wọn fi tu sawọn ọlọpaa RRS lọwọ.

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ banki to n gbabọde yii naa ti bọ sọwọ ọlọpaa l’Ekoo gẹgẹ bawọn agbofinro ṣe wi, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ banki to ti n ṣiṣẹ ati orukọ rẹ. Ipinlẹ Edo ni oṣiṣẹ banki keji wa, wọn loun ti sa lọ bo ṣe gbọ pe wọn ti mu awọn eeyan oun l’Ekoo, awọn ọlọpaa ni awọn ṣi n wa a, awọn yoo si ri i.

Ni ti awọn tọwọ ba yii, ọdọ awọn SARS ni wọn taari wọn si fun itọpinpin to nipọn.

Leave a Reply