Ẹ woju Azeez ati Adeọla to ji ọmọ ọdun mẹrinla gbe l’Owode-Ẹgba

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta           

Ahamọ ọlọpaa ni ẹka to n ri si ijinigbe ati lilo eeyan nilokulo ni CP Edward Ajogun ni ki wọn ko awọn ọmọdekunrin meji yii, Micheal Hammed Azeez; ẹni ogun ọdun ati ikeji ẹ, Adeọla Ogunṣẹyẹ; ẹni ọdun mejilelogun, ti wọn fipa ba ọmọdebinrin kan lo pọ lọ bayii.

Mọto yii wa fun tita Tokunbọ ni lati orileede Japan. Ọgọrun-un kan maili lo ti rin. Ẹ le pe nọmba yii fun alaye kikun: 08038369992

Ohun to gbe wọn debẹ ni ibalopọ ipa ti wọn ni wọn ṣe pẹlu ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinla kan lalẹ ọjọ kẹta, oṣu kọkanla yii, l’Owode-Ẹgba, ipinlẹ Ogun.

DSP Abimbọla Oyẹyẹmi to fidi ẹ mulẹ pe awọn ọmọkunrin meji yii ti wa latimọle, ṣalaye pe iya ọmọ ti wọn ṣe ṣakaṣaka naa lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Owode-Ẹgba, to si ṣalaye fun wọn pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ kẹta, oṣu yii, ni awọn meji naa ji ọmọ oun gbe lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.

Iya ọmọ yii sọ pe ibasun to lagbara ni wọn ṣe fọmọ oun. O ni Micheal ati Adeọla to tọọnu lori rẹ, wọn si ba a ṣere oge pẹlu tulaasi.

Oju ọna ileewe, l’Owode-Ẹgba, ni wọn ti pada ri ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa, nibi ti gbogbo ẹri ti foju han pe wọn ti ṣe e ṣakaṣaka pẹlu ibasun.

Ileewosan jẹnẹra Owode-Ẹgba naa ni wọn sare gbe ọmọge yii lọ, nibi ti wọn ti da itọju oriṣiiriṣii bo o.

Ifisun iya yii lo mu DPO teṣan ọhun, CSP Matthew Ediae, ko awọn ikọ rẹ lọ sile awọn ọmọ meji ti wọn fura si ọhun, afi bi wọn ṣe ba pata ọmọbinrin naa ninu yara wọn. Koda, pata ọhun ti ya nibi ti wọn ti n fagidi bọ ọ lati ṣe kinni fun un.

Ẹka to n ri si ijinigbe ati lilo eeyan nilokulo ni CP Edward Ajogun ni ki wọn ko awọn ọmọ meji yii lọ, fun itọpinpin si i ati gbigbe wọn lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply