Ẹ woju baba atọmọ to n jale n’Ipokia

Faith Adebọla, Ogun

 Ọpọ obi lo n daniyan lati fi iṣẹ rere le ọmọ wọn lọwọ, amọ ni ti baba arugbo ẹni ọdun marundinlọgọrin ti wọn porukọ ẹ ni Weniwọn Abioro yii, ole jija loun kọ ọmọ ẹ, oko ole ọhun si ni wọn ti mu oun atọmọ ẹ, Zaccheous Abioro, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, wọn ti wa lahaamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ bayii.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii, nigba tawọn afurasi naa yọ kẹlẹ wọnu oko to jẹ ti Alaaji Moruf Kaka, eyi to wa niluu Ihunbọ, nijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun.

Awọn aladuugbo kan to ri wọn nibi ti wọn ti n gbiyanju lati jade loko ọhun lẹyin ti wọn ti ji awọn dukia ẹni ẹlẹni tan, ni wọn pariwo ole le wọn lori, wọn si mu wọn, ni wọn ba ke sawọn ẹṣọ alaabo So-Safe lori aago.

Nigba ti wọn debẹ, wọn ri awọn ẹru ti wọn ji, lara ẹ ni iwe ilẹ meji, eroja ọkọ kan, ati awọn windo alumi ti wọn yọ feremu rẹ gbogbo.

Njẹ ki ni wọn fẹẹ fi awọn ẹru ti wọn ji ko yii ṣe, wọn ni awọn fẹẹ lọọ ta a fawọn ṣalẹ-ṣalẹ ti wọn maa n ra a ni, wọn tiẹ darukọ kọsitọma kan ti wọn lo maa n ra alumi lọwọ awọn, Ọgbẹni Bapa Madaki, ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Kia lawọn ẹṣọ So-Safe ti wa oun naa kan, ti wọn si gbe e janto.

Wọn lawọn afurasi naa ti jẹwọ pe loootọ lawọn n jale, ki wọn ṣaanu awọn.

Alukoro ileeṣẹ So-Safe sọ pe awọn ti fa awọn afurasi mẹtẹẹta le ọlọpaa lọwọ, o ni iṣẹ iwadii n tẹsiwaju lori wọn.

Leave a Reply