Ẹ woju Desmond, ayederu sọja, tọwọ tẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ayederu ṣọja kan, Desmond Ikechukwu.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, fidi rẹ mulẹ fawọn oniroyin pe ọwọ awọn tẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun pẹlu aṣọ ṣọja to wọ sọrun lagbegbe Ararọmi, niluu Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ọsẹ to kọja.

Salami ni iwadii ti awọn ṣe lori iṣẹlẹ ọhun fihan pe Desmond ko fi igba kankan dara pọ mọ ikọ ọmọ ologun ri, ó ni ṣe lo kan n faṣọ ṣọja to n wọ kaakiri ilu da ibẹru sọkan awọn eeyan, bẹẹ lo tun fi n lu awọn mi-in ni jibiti awọn nnkan ini wọn.

O ni ko ni i pẹ rara ti ọkunrin naa yoo foju bale-ẹjọ lẹyin tawọn ọlọpaa ba fọrọ wa a lẹnu wo tan.

Leave a Reply