Ẹ WOJU Ẹ: ẸNI TO PA TOLULỌPẸ AFẸRONPILEENI-JAGUN REE O

Ileeṣẹ ologun ofurufu ilẹ wa ti kede, lọṣan-an yii, oruko ẹni to pa Tolulọpẹ Arotile, ọmọbinrin akọkọ to n fi ẹronpileeni jagun nilẹ wa. Ki i ṣe pe wọn darukọ ẹ lasan, Alaroye paapaa ti wa aworan rẹ jade. Aworan ẹ niyi, oruko rẹ si ni Nehemiah Adejoh. Alukoro agba fun ileeṣẹ ologun ofurufu ilẹ wa (Nigeria Air Force), Ibikunle Daramọla, lo kede orukọ̀ ati aworan Adejoh niluu Abuja.

Daramọla ni Tolulọpẹ ti mọ awọn ọrẹ rẹ yii nigba ti wọn jọ n lọ si ileewe giramma ti awọn ologun ofurufu to n jẹ Air Force Secondary School to ti yi orukọ pada bayii di Air Force Comprehensive School ni Kaduna. O ni ileewe naa ni wọn jọ lọ.

Gẹgẹ bi alukoro naa ti wi, niṣe ni Nehemiah Adejoh, Igbẹkẹle Fọlọrunsọ ati Festus Gbayegun n wa mọto Kia Sorento kan bayii lọ, ni wọn ba sare kọja lara Tolulọpẹ nibi ti oun ti n rin lọ lodikeji ni tirẹ. Awọn mẹtẹẹta yii ki i ṣe ọmọ ogun ofurufu o, bẹe ni won ko gbe inu ọgba awọn ologun ofiurufu yii nigba ti wọn fi wa ni Kaduna yii, sifilian ni wọn, ita ni wọn ti n wa sileewe wọn. Ẹni kan  ni wọn waa wo ninu ọgba awọn ọmọ ogun yii, Arabinrin Chioma Ugwu, iyawo ologun ofurufu ti wọn n pe ni Chukwuemeka Ugwu, ti oun n gbe ninu ọgba awọn ọmọ ogun yii.

Bi wọn ti kọja lara Tolulọpe ni Adejoh ati awọn to ku da a mọ, ni Adejoh ba ki jia mọto si rifaasi, ki wọn le ba a ko too jade. Nibi to ti n sare rifaassi yii lo ti fi mọto kọlu Tolulọpẹ lati ẹyin, ti mọto naa si ti i ṣubu pẹlu agbara, nibẹ ni Tolu ti fori sọ okuta ti won fi da ọna naa. Yatọ siyẹn, mọto naa tun gun un lori, o si jẹ ko tubọ ṣeṣe si i.

Daramọla ni lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti sare gbe Tolulọpẹ lọ si ileewosan awọn ọmọ ogun ofurufu ninu ọgba nibẹ, nigba to si di aago marun-un ku iṣẹju mẹẹdogun, Tolulọpe jade laye. Kia ni wọn ti mu awon mẹtẹẹta yii, wọn si ti wọn mọle. Ohun ti wọn kọkọ ṣe fun wọn loju ẹsẹ ni pe wọn ṣe tẹẹsi fun wọn lati tmọ boya wọn ti muti, ṣugbọn ko si oorun ọti lẹnu wọn.  Ohun kan ti wọn pada ri ni pe Adejoh to wa mọto yi ko ni lansẹnsi ọkọ wiwa, o kan n wa mọto kiri ni tiẹ ni.

Alukoro awon ologun ofurufu naa sọ pe ẹjo yii ki i ṣe ti awon mọ, ẹjọ ọlọpaa ni, ileeṣe ologun ofurufu si ti taari rẹ si ọdọ wọn, awọn ọlopaa lo ku ti wọn yoo maa ba ẹjọ naa lọ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin …

One comment

  1. Samson Segun Olalere

    Ki Olorun ma fi was we sababi ibi. Ohun ti oju eniyan o to, kedere ni niwaju Oluwa. Ki Oluwa tu a won ebi Tolulope ninu.

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: