Ẹ woju Lawal, ogbologboo babalawo to n fi ẹran eeyan ṣetutu ọla l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ogbontarigi babalawo kan to p’orukọ ara rẹ ni Mojeeb Lawal, lo ti wa nikaawọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori ẹsun pe o n fi ẹran eeyan gun ọsẹ lati fi ṣe etutu ọla fawọn onibaara rẹ.

Lawal, lo wa lara awọn afurasi ọdaran marun-un tọwọ tẹ lori bi wọn ṣe n pa awọn ọlọkada nipakupa nipinlẹ Ondo, Ọṣun ati Kogi, lati ọdun 2023. Wọn aa si ji ọkada wọn gbe sa lọ lẹyin ti wọn ba pa wọn tan, ti wọn yoo si ju oku wọn sinu igbo lẹyin ti wọn ba ti ge ẹya ara ti wọn nilo lara wọn lọ.

Ninu alaye ti ọkunrin naa ṣe ni ALAROYE ti fidi rẹ mulẹ pe Lawal ni olori ẹgbẹ apaayan ọhun, iyẹn Dọlapọ Babalọla, maa n ko ẹya ara awọn eeyan ti wọn ba ti da ẹmi wọn legbodo fun lati fi gun ọsẹ etutu ọla fawọn to fẹẹ di olowo ojiji.

Koda, wọn tun fẹsun kan ọkunrin to loun tun n ṣiṣẹ ọdẹ ọhun pe oun funra rẹ ti pa ẹni kan sinu oko ri, o ge ori ẹni ọhun, eyi to lọọ gbe fun babalawo ẹgbẹ rẹ kan to pe ni Oluwo, ẹni ti wọn jọ fi ori olori yii joogun.

Ohun ti Lawal funra rẹ ba wa sọ ree nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.

‘‘Mojeeb Lawal lorukọ mi, iṣẹ babalawo ati ọdẹ ni mo yan laayo ju, ṣugbọn mo tun maa n bọ ogun lẹẹkọọkan.

‘‘Ọkan ṣoṣo ni t’emi ninu awọn sigidi mẹta ti wọn ko silẹ yii, bẹẹ ni mi o mọ ohunkohun nipa ọsẹ ti wọn tun ko siwaju wa.

‘’Inu oṣu Kẹta, ọdun 2024, ta a wa yii ni Dọlapọ waa ba mi. Ohun to sọ fun mi nigba naa ni pe iṣẹ ọlọpaa loun n ṣe nile-epo kan l’Abuja. O ni oun n fẹ iranlọwọ mi lori awọn nnkan kan, ti mo si jẹ ko ye e pe emi o mọ nipa nnkan to n beere lọwọ mi, nitori ẹran eeyan lo wọn ju lati ri. Bayii lo ṣe kuro lọdọ mi, to si ni ki n maa reti oun lọjọ karun-un si igba naa.

‘‘Oun lo mu ẹran eeyan wa pe ki n fi ba oun ṣoogun, o ni ẹran ara ọkan ninu awọn to fara gba ninu ijamba ọkọ loju ọna marosẹ loun ge, ti oun mu wa. Emi o mọ iru ẹya ara to mu wa o, nitori funra rẹ lo ko kinni ọhun sinu odo, to si gun un, ṣe l’emi kan ba a fi awọn eroja kan kun un, ti mo si ba a fi gun ọsẹ gẹgẹ bii ifẹ inu rẹ.

‘‘Emi o mọ iye awọn eeyan to fi ẹran ara wọn gun ọsẹ, bẹẹ ni mi o si ri i mọ lati ọjọ naa titi di ba a ṣe n sọrọ yii. Inu iwe ni mo ti ka bi wọn ṣe n fẹran eeyan gun ọṣẹ.

‘‘Lọjọ kan ni mo tun dẹ igbẹ ọdẹ lọ sinu igbo kan to wa lagbegbe Ita-Nla, niluu Ondo, ti mo si ṣe alabaapade oku kan ti wọn ti pa sibẹ. Nigba ti mo pada de ile ti mo si sọ ohun ti oju mi ri fun Oluwo to jẹ ẹnikeji mi, oun lo bẹ mi pe ki n jọwọ, lọọ ba oun ge ori oku naa wa, o ni oun fẹẹ lo o fun etutu kan.

‘‘Ẹẹmeji ni mo ba a lọ sinu igbo ọhun lati ba a gbe ori eeyan naa wale, ilaji rẹ ni mo ge nigba ti mo kọkọ lọ, lẹyin ọjọ kẹrin ni Oluwo tun bẹ mi lati lọọ baa mu ilaji yooku wa, ti mo si tun ba a ja awọn ewe kan to yẹ ko lo pẹlu rẹ bọ. Emi o paayan ni t’emi, ẹni ba pa eeyan nile-ẹjọ le ni ki wọn lọọ pa’’.

Ohun ti ALAROYE gbọ lati ẹnu ẹnikan to mọ Lawal daadaa ni pe ki i ṣe ilu Ondo gan-an lo n gbe gẹgẹ bii ohun to sọ fun wa lasiko ta a n fi ọrọ wa a lẹnu wo. Ẹni ọhun ni abule Òbòtò, eyi to wa loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, lo fi ṣebugbe, abule ọhun naa lo si ti n ṣiṣẹ awo to ni oun n ṣe.

Òbòtò yii si wa lara awọn ibi ti Dọlapọ to pe ara rẹ ni ọlọpaa fun Lawal lọọ ju oku ọlọkada kan to pa niluu Ondo si lẹyin to ti yọ awọn nnkan to nilo lara rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ipari oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lọwọ tẹ Dọlapọ, iyẹn ọdaju ọdaran to n pa awọn ọlọkada bii ẹni pa ẹran kaakiri, to si n ko ẹya ara wọn lọọ fun Lawal to jẹ babalawo rẹ.

Lawal nikan kọ lọwọ awọn agbofinro tẹ lori iṣẹlẹ ọhun, Oluwo to jẹ ọrẹ korikosun rẹ ninu iwa ọdaran atawọn meji mi-in ti wọn n ra ọja ole lọwọ tun tẹ pẹlu.

Orisiirisii oogun abẹnugọngọ, igba ọsẹ, sigidi nla nla mẹta atawọn nnkan mi-in lawọn ọlọpaa ba nikaawọ Lawal atawọn ẹmẹwa rẹ ninu iṣẹ awo tọwọ tẹ.

Leave a Reply